Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Maku 8-9 | Tani Jesu íṣe?>
Loni Maku 8 mu wá lọ si ipilẹ àwọn ti ó tẹ̀lé Kristi. Á ti tẹle Jesu ati àwọn ọmọ-ẹhin Rẹ̀ fun igba diẹ. Wọ́n tí ri àwọn iṣẹ́ iyanu, ìrọra aanu, wọ́n sì tẹ́tí sí ẹkọ rẹ pẹ̀lú. Nísinsìnyí àkókò ìpinnu tí dé. Áwọn ìbéèrè pàtàkì meji nìyí: Tani Jésù íṣe? Àti pe kíni ó gbà láti tẹ̀lée?
A bẹ̀rẹ̀ ni ẹsẹ 27:
“Jésù sì jáde, ati awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ lọ si awọn ìletò ti o wá ni agbègbè Kesarea Filippi: Ó sì bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ léèrè li ọ̀nà pé, ‘ Tani àwọn ènìyàn ǹfí mí pè?’ ”
Ìbéèrè ti o rọrùn nìyí. Àti pé ibiti gbogbo wa tí máa ǹ bẹ̀rẹ̀ nìyí nígbàtí a bá ǹ gbìyànjú lati ro ero ohun ti a gbagbọ nínú rẹ. Á o bẹ̀rẹ̀ pẹlu ohun ti a ti gbọ lati ọdọ awọn míràn. Awọn ọmọ-ẹ̀yìn fún wà ní idahun diẹ ti wọn ti gbọ: Diẹ ninu wọn sọ pe Jesu ni Johanu Baptisti tí a túnbí, tabi Elijah, tabi ọ̀kan nínú àwọn woli.
Ati loni awọn ènìyàn ní orísirísi ero lori eniti Jesu íṣe. Awọn Musulumi bu ọla fun Jesu bi wòlíì nla ti Allah - aláṣẹ tí a bì nípasẹ̀ wúńdíá kan. Àwọn Jù ní ìdàrúdàpọ̀ nipa Jesu - diẹ ninu wọn wò gẹ́gẹ́bí rabbi ti o dara, àwọn miran ríì gẹ́gẹ́bí aláìgbàgbọ́, lakoko ti ẹni púpọ̀ rí bí Mèsáyà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Hindus bọ̀wọ̀ fun Jésù bi guru si awọn eniyan Ju, lákòókò ti ọpọlọpọ awọn Buddhist ka Jesu bi ẹni ti o tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé. Nitorina awọn ìmọ̀ràn pupọ ní wọn mú wa nipa Jesu - àwọn èyí tí ó wúni lórí púpọ̀. Ṣùgbọ́n ni ẹsẹ 29, Jesu tẹ síwájú nípa ọrọ náà:
“ ‘ Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, ṣùgbọ́n kini ẹ̀yin tí wí’? ‘ Tani ẹ sọ pe emi jẹ? ’ ”
Ìbéèrè kàǹkà ní èyí. Kí ìgbàgbọ́ tó lè ní ìtumọ̀, o ni láti jẹ èyí tí ó tí ọkàn oníkálukú wá. Kò tọ́ lati mọ̀ ohun ti àwọn míràn sọ. Ò ni lati wa láti ọkàn oníkálukú: Tani o sọ pe Jesu ìṣe?
Èyí jẹ akoko ipinnu, àti pé Peteru sọ tìrẹ:
“Pétérù sì dáhùn pé, "Ìwọ Ni Mèsáyà"
Eyi jẹ akoko nla kan. Mèsáyà tumọ sì ẹni tí a fi òróró yan. Òun ni Ọlọrun ti yan lati mú awọn ìlérí rẹ ṣẹ ati pari eto nla rẹ lati fipamọ. Á ó máa wà sinu awọn ileri ati awọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọrun ni irin-ajo wa t’ókàn. Ni bayi, jẹ́kí ó yè ọ pe ìkéde Pétérù ni okuta ipilẹ fun igbagbọ. Bí a ṣe ǹ bá Ọlọrun rìn bẹrẹ pẹlu ẹniti a sọ pe Jesu ìṣe.
Ati ni ẹsẹ 31, Jesu kọ wọn pe Mèsáyà...
... gbọ́dọ̀ jiya ọpọlọpọ awọn ohun ati pe yíò sí di ìkọ̀sílẹ̀ nípasẹ̀ awọn alàgbà.
Jésù kò fẹ́ ya wọn lẹnu nígbàtí àyànfẹ́ Ọlọrun bá dì ìkọ̀sílẹ̀ nipasẹ awọn oludari,alágàbàgebè
...ati pe a gbọdọ pá ati lẹhin ọjọ kẹta kí ó jíǹde”
Nitori náà Jesu gbe gbogbo rẹ jade. Á ó pá Òun àti pé ní ọjọ́ kẹta Òun yíò jíǹde. Àsọtẹ́lẹ̀ tí wá fún bí awọn ọgọrun ọdun, nínú ìwé Aísáyà 53, Orin Dafidi 22, Sakaráyà 12. Eto Ọlọrun ni. Àgbélébù n bọ lọ́nà.
Ó dùn létí láti gbọ́, àgbélébù ní ó ṣe ìpínyà Jésù tí Bíbélì kúrò ninu ohun ti awọn míràn ǹsọ. Àwọn Mùsùlùmí kò gbà gbọ̀ nínú itan agbelebu; Hindus sọrọ nipa Jesu ti nkọja lọ si samadhi alaafia; bẹ́ẹ̀ ní awọn Buddhist ko gbagbọ ninu ẹ̀ṣẹ̀, àgbélébù jẹ ohun tí ó burú jọjọ.
Ní àkọ́kọ́, Pétérù ni irufẹ èrò bẹ́ẹ̀. Ó bá Jésù wí ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n Jésù bá Pétérù wí bí ó ṣe ǹronú bi eniyan, tí kò náà-ní awọn ohun Ọlọrun. Ìrònú ènìyàn yíò gbá ènìyàn ti o dara lọwọ ìjìyà, nígbàtí awọn eniyan búburú yíò gba ohun ti o tọ si wọn. Ṣugbọn tí Jésù kò rí bẹ́ẹ̀. Jésù gbé ìgbé ayé ódodo, o sì gbá iku ẹlẹṣẹ kú. O gba ipò wá gẹ́gẹ́bí ẹlẹṣẹ.
Lẹhin náà ní ẹsẹ̀ 34, “Jesu ṣàlàyé ǹkan tó gbà láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Rẹ̀. Fara balẹ̀ kà á:
“Ẹnikẹ́ni tó bá ma jẹ́ ọmọlẹ́yìn mi gbọ́dọ̀ sẹ́ ara rẹ̀ kí ó gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó sì tẹ̀lé mi.”
Tí o bá ma tẹ̀lé Jésù, há ẹsẹ̀ Bíbélì yí sórí. Èyí ni ìdíyelé. Láti tẹ̀lé Jésù, o gbọ́dọ̀:
Sẹ́ ara à rẹ:O kò lè gbà ara rẹ là, o ko le dara tó lójú Ẹlẹda. Ó nílò Jesu.
Gbé àgbélébù rẹ:Kristiẹni kọ̀ọ̀kan ló ní ẹrú láti gbé, àti ẹbọ láti rú. Kò sí ìgbésí ayé tí ó rọrùn.
Kí ó sì tẹ̀lé Jésù:Níbi tí Jésù bá tí síwájú, ìwọ lo tẹ̀lé e.
Àti tẹ̀lé Jésù gbéwọ̀n díẹ̀ ju kí a kàn gbàgbọ́ lọ, gẹ́gẹ́bí ìgbéyàwó ti ju ìmọ̀lára lọ. Ó jẹ́ ohun tí à ní láti fi ara jìn fún ní ojojúmọ́, májẹ̀mú tí a fi ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ dá. Ẹsẹ̀ 35:
“Nítorí ẹnikẹni ti o ba fẹ gba ẹmi rẹ̀ là yíò sọ ọ nù, ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmi rẹ̀ nù nítorí mi ati nítorí ihinrere òun náà ní yio gbá la. Nítorípé ère kíni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ẹ̀mí nù? Tabi kini ènìyàn ibà fí ṣé paṣipaarọ ẹmi rẹ̀? ”
Mo nífẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ Bíbélì yẹn. Ṣe o mọ ohun ti Jesu n sọ? O n sọ pe ẹmi rẹ ní iye lórí ju gbogbo àgbáyé lọ. Nitorina ẹ jẹ ki a kọ ehin sí ohùn ayé ki a rọ̀ mọ́ Jésù. Lójú Jesu, ẹmi rẹ to lati kú fún. Lójú tìrẹ kíni ìdíyelé rẹ̀?
Nínú ìgbésí ayé tèmi, mo fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣòfò pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn láti fi ìgbàgbọ́ sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn míràn, “Wọ́n gba èyí àti èyíinì gbọ́.”� Ṣugbọn ìpinnu de ní ọjọ́ kan - fún ìgbàgbọ́ tèmi. Iyatọ nla wà láàrin ìgbàgbọ́ ninu ìgbéyàwó ati wíwà nínú ìgbéyàwó. Àti pé ìyàtọ̀ ńlá wà láàrin gbígba ohun kan gbọ́ nípa Jésù àti títẹ̀lé Jésù. Ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni ìfarajì ati ìrúbọ. Ni kúkúrú, ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni ìgbésí ayé rẹ. Gbogbo ìṣẹ́jú-àáyá inú rẹ̀ ló ṣe iyebíye.
Ka Mark 8, kí ó sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí òní. Tani ìwọ ń sọ pé Jésù jẹ́, àti pé ǹjẹ́ ìwọ ṣetán láti tẹ̀lé e?
Fún Ìrònú àti Ìjíròrò
- Tani ìwọ ń sọ pé Jésù jẹ́?
- Kini yíò nọ́ ọ láti tẹ̀lé Jésù? Kọ ẹsẹ̀ 34 sílẹ̀ ní èdè tìrẹ fún ìgbé ayé rẹ?
- . Ǹjẹ́ títẹ̀lé Jésù tó ìdíyelé rẹ? Kọ àwọn ẹsẹ̀ 35-36 ní èdè tìrẹ fún àmúlò ní ìgbésí ayé rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More