Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Maku 6-7 | A Rán Ni Láti Sìn
A wà ní Maku 6 lónì, àkòkò sì ti tó k'á ta'yò. Títẹ̀lé Jésù kò fì'gbà kan jẹ́ eré tí à ń jẹ́ olùwòran níbẹ̀, ní báyìí àsìkò tó kí àwọn ọmọ ẹ̀hìn t'ayò.
Ọ̀rọ̀ yí kan ìwọ pàápàá. Tí o bá ń tẹ̀lé Jésù. a pè ọ́ sí iṣẹ́ ìránṣẹ́, a kò sì dá ẹnikẹ́ni sí. Tí o kò bá wá jẹ́ onígbàgbọ́, ìpè náà ṣí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n fi s'ọ́kàn pé a kò pè ọ́ láti dara pọ̀ mọ́ àgbékàlẹ́ kan, a pè ọ́ láti dara pọ̀ mọ́ èètò ìtẹ̀síwájú .
Kí leléyìí túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn? Wọn kò ní pẹ́ rí i. Maku 6, ẹsẹ 7:
“Ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó rán wọn lọ ní meji-meji, ó fi àṣẹ fún wọn lórí àwọn ẹ̀mí èṣù. ”
Ṣàkíyèsí pé Jésù rán wọn jáde ni. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ kìí dúró pé kí àwọn ènìyàn wọlé wá, ó máa ń jáde lọ sí'bi tí wọ́n ti nílò rẹ̀ ni. Ó sì rán wọn ní méjì méjì - eré ìdárayá àkẹ́gbẹ́ ṣe ni iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ó sì fún wọn ní àṣẹ - àṣẹ ti Ọlọ́run pé- lọ.
Ó sì fún wọn ní ìlànà. Ẹsẹ 8:
“Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má mú ohunkohun lọ́wọ́ ní ọ̀nà àjò náà àfi ọ̀pá nìkan. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, tabi ìgbànú, tabi kí wọn fi owó sinu àpò wọn.”
Iṣẹ́ wọn àkọ́kọ́ jẹ́ ẹ̀kọ́ nínú ìgbàgbọ́. Má mùú ohunkóhun - àfi ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n ìlànà kò rí bákan náà ní gbogbo ìgbà. Nígbà míràn Jésù rán wọn níṣẹ́ pẹ̀lú ìpèsè. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ kìí ṣe àgbékalẹ̀ tàbí bíi èròjà, ìrìnàjò ni, ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo sì ní kí o gba ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa nígbà gbogbo. Títẹ̀lé Jésù lẹ́hìn túmọ̀ sí títẹ̀lé ìlànà, kí á sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nígbà gbogbo. Yálà ọwọ kún ni tàbí ó ṣófo, gbẹ́kẹ̀lẹ́ Ọlọ́run láti pèsè. Yálà a ṣaláìní ni tàbí a ní ànító, k'á gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti pèsè.
Báwo ni a ó ti ṣe é? Ẹsẹ 12:
“Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ti ń lọ, wọ́n ń waasu pé kí gbogbo eniyan ronupiwada. Wọ́n ń lé ọpọlọpọ ẹ̀mí èṣù jáde, wọ́n ń fi òróró pa ọpọlọpọ aláìsàn lára, wọ́n sì ń mú wọn lára dá.”
Wọ́n ṣe bẹ́ ẹ̀. Wọ́n ní ìgbàgbọ́, Ọlọ́run ṣì pèsè. Wọ́n padà tọ Jésù láti j'ábọ̀ fún Un, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọ̀pọ̀ èrò ti péjọ, ní ẹsẹ 31, Ó sọ fún àwọ̀n ọmọ ẹ̀hìn pé,
“Ẹ wá kí á lọ sí ibìkan níkọ̀kọ̀, níbi tí kò sí eniyan, kí ẹ sinmi díẹ̀.”
Òfin iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó ṣe pàtàkì níbí yìí ni: sinmi pẹ̀lú Jésù. Wọ́n lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, ṣùgbọ́n àwọn èrò ti ṣaájú wọn dé'bẹ̀! Ẹ má bínú o ẹ̀yin arákùnrin - àyè ìsinmi kò sí lọ́wọ́ tí a wà yí. 34
“Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é.”
Bí àánú Jésù ṣe pọ̀ yí máa ń ṣe mí ní kàyéfì. Àánú túmọ̀ sí "k'á jìyà pẹ̀lú" - Jésù ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ó rí àìní àwọn ènìyàn ara sì ta á. Ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn láti máa ṣe ìtara.
Nígbà tí Jésù yó fi kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ tán ilẹ̀ ti ṣú. Èrò lọ́pọ̀ yanturu - látọ̀ná jínjìn - wọ́n nílò oúnjẹ. Àwọn ọmọ ẹ̀hìn sọ fún Jésù pé k'ó ní kí gbogbo àwọn èrò máa lọ sílé wọn. Ohun t'ó bójú mu ni. Ẹsẹ 37:
“Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, ‘“Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.”
Fi'yè sí èyí. Àwọn ọmọ ẹ̀hìn ṣ'àkíyèsí àìní, Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n bọ́ àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ohun t'ó wà kò tó. Kò tiẹ̀ lè tó rárá ni! Ọ̀nà wọn sì jìn sí ìlú kankan.
Ṣùgbọ́n rántí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́: ọwọ́ òfìfo tí ó kún fún gbogbo ohun tí a nílò, gbẹ́kẹ̀le Ọlọ́run fún ìpèsè. Ẹsẹ 38:
“‘Àkàrà mélòó lẹ ní?’” Ó bèèrè. ‘Ẹ lọ wádìí.’ Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n ní, 'Márùnún - àti ẹja méjì. ’”
Àkàrà àti ẹja fún ẹ̀tahóró nìyẹn, kìí ṣe fún ẹgbẹẹ̀gbẹ̀rún ènìyàn. Ṣùgbọn máa w'òye o. Wọ́n sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí wọ́n jókòó, ni ẹsẹ 41,
“Jesu bá mú àkàrà marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu àkàrà náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. ”
Dúró ná. Gb'ọ́wọ́ lé fọ́nrán yẹn ná kí o sì ṣàkíyèsí. Jésù dúpẹ́, ó bu àkàrà náà, ó sì fún ọmọ ẹ̀hìn kọ̀ọ̀kan - mélòó?
Fi'ra rẹ s'ípò wọn. Kíló wà lọ́wọ́ rẹ - bóyá ìdajì àkàrà pẹ̀lú ẹja kíńkínní. B'ojú wò'kè - ọgọọgọ̀rún ènìyàn. Ṣùgbọ́n Jésù ní kí o bọ́ wọn, nítorí náà, o bọ́ wọn: 42
“Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó àjẹkù àkàrà ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá. Iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn”
. Èyí wuyì. Irú ẹ̀ sì tún ń ṣẹlẹ̀. Mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ ìtàn nípa àkàrà àti ẹja lójú ayé láti ẹnu àwọn ọ̀rẹ́ mi t'ó wà nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ṣíse ọ̀nà ìdẹ́ra fún àwọn tí ìjì líle ṣ'ọṣẹ́ fun ní apá Àréwá, bíbọ́ àwọn aláìní ní Mexico, àti àimoye irú rẹ̀. Ìgbà míràn ọkọ̀ ńlá yóò kàn dédé yọ láti ibi tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀. Ìgbà míràn, nnkan kékeré yóò pẹ́ ju b'ó ti yẹ lọ k'ó tóó tán. Àwọn ojúlówó ìṣẹ́ ìyanu - ṣùgbọ́n wọn ń ṣẹlẹ̀ láàrin bíbá àìní pàdé. Nígbogbo ìgbà nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ àánú.
Bí o ti ń ka Maku 6 àti 7, fi iyè sí àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù. Ṣé ó ń ṣe àṣehàn ni - àbí ó ń fi àánú hàn?
Ó ti pẹ́ tí mo ti mọ̀ pé mi ò tó nnkan kan. Ṣùgbọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ ìpè sí nnkan t'ó tóbi ju àwa fúnrara wa lọ, a ò leè dáa ṣe.
Ìwọ ń kọ́? Ṣé o ní àmúyẹ láti ran àwọn ènìyàn yìí lọ́wọ́? Rárá. Èmi pàápàá kò ní. Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé kí á lọ, nítorí náà, jẹ́ ká lọ. Yálà lọ́wọ́ òfìfo ni tàbí pẹ̀lú ọwọ́ tó kún, gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run... kí o sì darapọ̀ mọ́ eré náà.
Fún Àṣàrò àti Ìjíròrò:
- Kí lo rò pé Jésù ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn nígbà tí ó rán wọn jáde láì mú owó lọ́wọ́? Nígbà t'ó ní kí wọ́n bọ́ ẹgbẹ̀rún márùnún ènìyàn pẹ̀lú oúnjẹ tó kéré jọjọ ńkọ́? Njẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ yẹn ṣì wúlò lónìí?
- Kínni ìrírí rẹ pẹ̀lú sísin Ọlọ́run àti ríran àwọn míràn lọ́wọ́. Ṣe alábàápín ìtàn re.
- Tí nnkan kan bá wà tí o leè ṣe fún Ọlọ́run, kínni yóò jẹ́?
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More