Kol 2
2
1NITORI emi nfẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ bi iwaya-ìja ti mo ni fun nyin ti pọ̀ to, ati fun awọn ará Laodikea, ati fun iye awọn ti kò ti iri oju mi nipa ti ara;
2Ki a le tu ọkàn wọn ninu, bi a ti so wọn pọ̀ ninu ifẹ ati si gbogbo ọrọ̀ ẹ̀kún oye ti o daju, si imọ̀ ohun ijinlẹ Ọlọrun ani Kristi;
3Inu ẹniti a ti fi gbogbo iṣura ọgbọ́n ati ti ìmọ pamọ́ si.
4Eyi ni mo si nwi, ki ẹnikẹni ki o má bã fi ọ̀rọ ẹtàn mu nyin ṣina.
5Nitoripe bi emi kò tilẹ si lọdọ nyin li ara, ṣugbọn emi mbẹ lọdọ nyin li ẹmí, mo nyọ̀, mo si nkiyesi eto nyin, ati iduroṣinṣin igbagbọ́ nyin ninu Kristi.
Ìgbé-Ayé Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu Kristi
6Nitorina bi ẹnyin ti gbà Kristi Jesu Oluwa, bẹ̃ni ki ẹ mã rìn ninu rẹ̀:
7Ki ẹ fi gbongbo mulẹ, ki a si gbe nyin ro ninu rẹ̀, ki ẹ si fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ nyin, gẹgẹ bi a ti kọ́ nyin, ki ẹ si mã pọ̀ ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ.
8Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe fi ìmọ ati ẹ̀tan asan dì nyin ni igbekun, gẹgẹ bi itan enia, gẹgẹ bi ipilẹṣẹ ẹkọ aiye, ti ki iṣe bi ti Kristi.
9Nitoripe ninu rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara.
10A si ti ṣe nyin ni kikún ninu rẹ̀, ẹniti iṣe ori fun gbogbo ijọba ati agbara:
11Ninu ẹniti a ti fi ikọla ti a kò fi ọwọ kọ kọ nyin ni ila, ni bibọ ara ẹ̀ṣẹ silẹ, ninu ikọla Kristi:
12Bi a si ti sin nyin pọ̀ pẹlu rẹ̀ ninu baptismu, ninu eyiti a si ti jí nyin dide pẹlu rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu iṣẹ Ọlọrun, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú.
13Ati ẹnyin, ẹniti o ti kú nitori ẹ̀ṣẹ nyin ati aikọla ara nyin, mo ni, ẹnyin li o si ti sọdi ãye pọ̀ pẹlu rẹ̀, o si ti dari gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin;
14O si ti pa iwe majẹmu nì rẹ́, ti o lodi si wa, ti a kọ ninu ofin, eyiti o lodi si wa: on li o si ti mu kuro loju ọ̀na, o si kàn a mọ agbelebu;
15O si ti já awọn ijọba ati agbara kuro li ara rẹ̀, o si ti dojuti wọn ni gbangba, o nyọ̀ ayọ̀ iṣẹgun lori wọn ninu rẹ̀.
16Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi:
17Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara.
18Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi adabọwọ irẹlẹ ati bibọ awọn angẹli lọ́ ere nyin gbà lọwọ nyin, ẹniti nduro lori nkan wọnni ti o ti ri, ti o nti ipa ero rẹ̀ niti ara ṣeféfe asan,
19Ti kò si di Ori nì mu ṣinṣin, lati ọdọ ẹniti a nti ipa orike ati iṣan pese fun gbogbo ara, ti a si nso o ṣọkan pọ, ti o si ndagba nipa ibisi Ọlọrun.
Ìgbé-Ayé Titun ninu Kristi
20Bi ẹnyin ba ti kú pẹlu Kristi kuro ninu ipilẹṣẹ aiye, ẽhatiṣe ti ẹnyin ntẹriba fun ofin bi ẹnipe ẹnyin wà ninu aiye,
21Maṣe fọwọkàn, maṣe tọ́wò, maṣe fọwọbà,
22(Gbogbo eyiti yio ti ipa lilo run), gẹgẹ bi ofin ati ẹkọ́ enia?
23Awọn nkan ti o ni afarawe ọgbọ́n nitõtọ, ni adabọwọ ìsin, ati irẹlẹ, ati ìpọn-ara-loju, ṣugbọn ti kò ni ere kan ninu fun ifẹkufẹ ara.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Kol 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.