Kol 3

3
1NJẸ bi a ba ti ji nyin dide pẹlu Kristi, ẹ mã ṣafẹri awọn nkan ti mbẹ loke, nibiti Kristi gbé wà ti o joko li ọwọ́ ọtun Ọlọrun.
2Ẹ mã ronu awọn nkan ti mbẹ loke kì iṣe awọn nkan ti mbẹ li aiye.
3Nitori ẹnyin ti kú, a si fi ìye nyin pamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun.
4Nigbati Kristi, ẹniti iṣe ìye wa yio farahàn, nigbana li ẹnyin pẹlu o farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ogo.
5Nitorina ẹ mã pa ẹ̀ya-ara nyin ti mbẹ li aiye run: àgbere, iwa-ẽri, ifẹkufẹ, ifẹ buburu, ati ojukòkoro, ti iṣe ibọriṣa:
6Nitori ohun tí ibinu Ọlọrun fi mbọ̀wa sori awọn ọmọ alaigbọran.
7Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti nrìn nigbakan rí, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi.
8Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin.
9Ẹ má si ṣe purọ́ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣe rẹ̀;
10Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a:
11Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo.
12Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra;
13Ẹ mã farada a fun ara nyin, ẹ si mã dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sun si ẹnikan: bi Kristi ti darijì nyin, gẹgẹ bẹ̃ni ki ẹnyin ki o mã ṣe pẹlu.
14Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, ti iṣe àmure ìwa pipé.
15Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mã ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ.
16Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa.
17Ohunkohun ti ẹnyin ba si nṣe li ọ̀rọ tabi ni iṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn li orukọ Jesu Oluwa, ẹ mã fi ọpẹ́ fun Ọlọrun Baba nipasẹ rẹ̀.
Ìbálò Onigbagbọ pẹlu Ara Wọn
18Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi o ti yẹ ninu Oluwa.
19Ẹnyin ọkọ, ẹ mã fẹran awọn aya nyin, ẹ má si ṣe korò si wọn.
20Ẹnyin ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin li ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa.
21Ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu, ki nwọn má bã rẹwẹsi.
22Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara li ohun gbogbo; kì iṣe ni arojuṣe, bi awọn alaṣewù enia; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibẹ̀ru Ọlọrun:
23Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, kì si iṣe fun enia;
24Ki ẹ mọ̀ pe lọwọ Oluwa li ẹnyin ó gbà ère ogun: nitori ẹnyin nsìn Oluwa Kristi.
25Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣe aiṣododo, yio gbà pada nitori aiṣododo na ti o ti ṣe: kò si si ojuṣãju enia.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Kol 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa