Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ
Nígbà tí a bá m'ẹ́nu ba ádùrá, kíni ó wá sí ọ lọ́kàn? Nígbà tí o bá gb'àdúrà, kíni ohun tí o fẹ́ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run? Àwọn ohun ẹ̀bẹ̀ wo lo má n bèrè nígbà gbogbo?
Ádùrá òtítọ́ máa ń wáyé ní ìkòríta ìjọ̀wọ́ àti ayẹye. Ádùrá ju ìbéèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run lásán, bíi wípé ò ń retí kí Ó dáhùn gbogbo ìfẹ́ rẹ torí Ó l'ágbára rẹ̀. Irúfẹ́ ádùrá yìí máa ń fi ọ́ s'àárín, á sì mú Ọlọ́run dàbí ìránṣẹ́. Ọlọ́run kọ́ lo fẹ́. Ọgbọ́n Rẹ̀ kọ́ lo fẹ́ rí gbà. Ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ kọ́ ni ọkàn rẹ ń fẹ́. Ohun tí o fẹ́ ni kí Ọlọ́run fi agbára Rẹ̀ dáhùn gbogbo ẹ̀bẹ̀ rẹ nítorí ìwọ lo mọ ohun tí o fẹ́ l''áyé rẹ, Ọlọ́run sì l'ágbára láti ṣe é.
Irú ádùrá yìí ni wàá gbà nígbà tí o bá gbàgbé wípé Ọlọ́run, Asèdá àti Olùgbàlà, mọ ohun tí o nílò jù ẹ́ lọ. Nítorí ádùrá yìí dá lé lórí àwọn ìfẹ́ àti àìní rẹ, kìí ṣe ádùrá tòótọ́. Nínú ádùrá òtítọ́, wà á jọ̀wọ́ ayé rẹ fún gbogbo ètò àti ìlànà Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní òye ju tìrẹ lọ. Wà á tẹrí ìfẹ́ rẹ ba sí ti Rẹ̀. Kìí ṣe wípé Ọlọ́run máa dáhùn ẹ̀bẹ̀ rẹ, ìwo lo máa jọ̀wọ́ ayé rẹ fún-un.
Ádùrá á wá jẹ́ ayẹyẹ. Nínú ádùrá, wà á má a ṣe àjoyọ̀ nínú ohun tí ó tùnmọ̀ sí láti jẹ́ ọmọ Baba wa l'ọ́run. Ayọ̀ á kún inú rẹ nítorípé Ó ti yàn láti fún ọ ní ìjọba Rẹ̀. Ó máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọ wípé Ó ń fi agbára nlá Rẹ̀ bá gbogbo àìní rẹ pàdé. Wà á ṣe àjoyọ̀ ìdáríjí, ìdáńdé, ìyípadà, ìmúláradá àti ore-ọ̀fẹ́. Wà á rí ayọ̀ nínú wípé Ó ká ẹ́ mọ́ àwọn eni tí ń ṣe iṣẹ́ ìràpadà Rẹ̀. O ní ìrètí ọjọ́ iwájú ológo tí ń bọ̀. Nítorí wípé Immanuẹli ti fi ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ fún ọ, yóò wà pẹ̀lú rẹ títí ayé àìnípẹ̀kun. Èyí fún ọ ní àláfíà, wípé ore-ọ̀fẹ́ yìí túnmọ̀ sí wípé a kò fi ọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ̀n, agbára àti ìwa-mímọ́ rẹ. O jíròrò lórí ógo àti ire Ọlọ́run, ọ sì yọ̀. O kò ní láti má a wá ìyè nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, ènìyàn tàbí àyíká rẹ nítorípé a ti fún ọ ní ìfẹ́ - ìyè àìnípẹ̀kun.
Ǹjé ádùrá òtítọ́ á a fi àyè gba ìbéèrè ẹ̀bẹ̀ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run bí? Bẹ́ẹ̀ni. Ọlọ́run fún ra Rẹ̀ gbà wá níyànjú láti kó gbogbo àníyàn wa lé òhun, nítorí ó tọ́ju wa. Àmọ́ gbogbo ìjírẹ̀bẹ̀ ádùrá òtítọ́ máa wáyé nínú ìjọ̀wọ́ àti ayẹye. Èyí ni ó máa yọ ìkùnsínú àti ìbéèrè ìmọ̀ t'ara eni nìkan kúrò nínú ẹ̀bẹ̀ wa. Irú ádùrá yìí ni ohun èlò ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú ayé rẹ. Nígbà tí o bá fi Ọlọ́run sí àyè Rẹ̀, tí o sì ń yọ̀ ní ipò rẹ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Rẹ̀, ádùrá á jẹ́ ohun èlò tí Ọlọ́run á fi tú ọ sílẹ̀ nínú ìgbèkùn ara rẹ. Èyí ni ore-ọ̀fẹ́!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.
More