Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 4 nínú 12

Gbogbo wa ni a máa ńṣe é, ó sì ṣeé ṣe kójẹ́ l'ójojúmọ́. A kò ní òye pé à ńṣe é, bẹ́ẹ̀ sì ni ó ní ipa ńlá tí ó ń kó lórí bí a ṣe rí ara wa ati bí a ṣe ń fèsì fún àwọn ẹlòmíràn. O jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn ìdí tí wàhálà ma fi ń wà nínú àjọṣepọ̀ pàápàá nínú ilé Ọlọ́run. Kíni ohun tí a máa ń sábà ṣe yi tí o máa ń fà ìpalára báyìí? Èyí tí a sì máa ń gbàgbé.

Nínú hílàhílo àti ìmọtaraẹninìkan ayé wa, ó jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn pé a máa ń gbàgbé bí àánú tí bùkún tí ó sì tún ṣe ìmúbọ̀sípò tó nípọn nínú ayée wa. Òtítọ́ pé Ọlọ́run ti bùkún-un wa pẹ̀lú ojú rere Rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ìbínú Rẹ̀ ló tọ́ sìwa máa ń tètè kúrò ní ìrántí wa bíi orin tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí tí a ko si rántí mọ́. Òtítọ́ ni wípé ni àràárọ̀ ni àánú ọ̀tún máa ń yọ kí wá kì í ṣe ohun tí ó ń mú wá l'ọkàn bí a ti ń sa sókè sódò ni ìpalẹ̀mọ́ fún ọjọ́ wa. Bí a bá ti forí lélẹ̀ ni opin ọjọ́ fún oorun tí a nílò lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń kùnà láti bójú w'ẹ̀hìn wo ọ̀gọọ̀ọrọ̀ àánú tí ó ti ọwọ́ Ọlọ́run kán s'orí ayé kékeré wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a kìí fi àyè sílè láti jókòó ṣ'àṣàrò l'óríi bí ayé wa ìbá ti rí tí a kò bá kọ àánú Olùgbàlà sínú ìtan ayé wa. O bá ní lọ́kàn jẹ́ pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a máa ń jé ẹni tí ń gbàgbé àánú. Gbígbàgbé àánú lewu nítorí wípé ó máa ń ṣe àpèjúwe bí a ti ń ronú nípa ara wa àti nípa ẹlòmíì.

Bí ó bá rántí àánú, óò rántí pẹ̀lú wípé ó kò ṣe ohunkóhun láti j'ogún ohun tí àánú tí fi bùkún fún ọ. Bí ó bá rántí àánú, ó máa ní ìrẹ̀lẹ̀, èmi ìdúpẹ́, ó sì máa tútù. Bí ó bá rántí àánú, kíkùn a yẹra fún ẹ̀mí ìmoore àti pe ìmọtaraẹni nìkan a yẹra fún ìjọ́sìn. Ṣùgbọ́n bí ó bá gbàgbé àánú, óò fi ìgbéraga sọ fún ara rẹ pé ohun tí ó lépa ló tẹ̀ ọ lọ́wọ́. Bí ó bá gbàgbé àánú, ó má máa gba ìyìn fún ohun tí àánú nìkan lè ṣe. Bi o bá gbàgbé àánú, ó sọ ara rẹ di olódodo àti ẹni yíyẹ, óò sì máa gbé ilé ayé bíi wípé ìwọ ni ó tọ si àti bí apàṣẹ wàá.

Bí ó bá gbàgbé àánú, tí ó sì ro wípé ó ní àmúyẹ, ó máa rọrùn fún ọ láti má lè na ọwọ́ àánú sí àwọn ẹlòmíràn. Ní ìgbéraga, ó lérò wípé ohun tí ó tọ́ sì wọn ní wón ń rí gbà gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà tí ń gba ohùn tí ó tọ́ sì ọ. Ọkàn ìgbéraga rẹ kò tútù, nítorí náà o máa ń ṣòro kí ọ̀ràn ẹlòmíì tó mì ọ. Ó ń gbàgbé pé fífarajọ ni ó fara jọ arákùnrin rẹ tí ó wà nínú àìní, ní kíkúnná láti gba wípé kò sí ọkàn nínú yín tí ó dúró nínú àmúyẹ níwájú Ọlọ́run. Ìrẹ̀lẹ̀ ni erùpẹ̀ tí àánú fún ẹlòmíràn ń lo láti dàgbà. Èmi ìmoore fún àánú tí a fífún wá jẹ́ ìwúrí fun àánú púpọ̀ síi. Paulu wipe, “ Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi.” (Ìwé Éfésù orí kẹ́rin ẹsẹ̀ kéjìlélọ́gbọ̀n ).

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/