Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 7 nínú 12

Jẹ́kí a jọ jíròrò fúngbà díẹ̀. Ṣé ìgbésí-ayé ìbùkún ni ìwọ ńgbé àbí ti atótónu? Ó rọrùn láti máa kùn. Àti wá ẹ̀bi kò ṣòro. Bẹ́ẹ̀ni àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn wà ní àrọ́wọ́tó. Kò le rárá láti rí àwọn ǹkan tí kò pójú òṣùwọ̀n bí o ti fẹ́. Ó rọrùn gidigidi láti máa kanra pẹ̀lú àìní sùúrù. Àti máa járí mọ́lẹ̀ nípa ìṣòro ayé kò ṣòro. Kìí pẹ́ rárá fún ǹkan láti tojú sú ènìyàn.

Èíṣe tí àwọn ǹkan wọ̀nyí fi wá rí bẹ́ẹ̀? Wò ó, ẹ̀ṣẹ̀ ló mú àwọn ǹkan wọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀ nínú ayée wa. Nítorí kìkìdá ìmotara-ẹni-nìkan ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, ọ̀pọ̀ nínú wa ló ṣì máa ń gé ìrònú wa kúrú síbi ǹkan tí a fẹ́, tí a nílò, àti ìmọ̀lára wa pẹ̀lú. Lọ́pọ̀ ìgbà la ma ń gbé òṣùwọ̀n bí ayée wa ti da sí lóríi bóyá gbogbo ìfẹ́ wa ni a múṣe. Bí a ti ń rìn ká, ìdánwò láti gbé ìgbé-ayé èmi-nìkan-ni kìí jìnà sí sàkánì wa. Tí o bá ti fi ara rẹ ṣe agbátẹrù ìgbésí ayéè rẹ, oríṣiríṣi ǹkan tí yóò mú ìkùnsínú wá lo ó ma rí.

Òtítọ́ mìíràn ni wípé ayé yìí ti wá sorí kodò ní ìkùnà sí bí Ọlọ́run ti ṣètò rẹ̀. Ayé yìí ti forí ṣọ́pọ́n lóòótọ́. Ǹkan kò fara rọ. Oríṣiríṣi wàhálà lo ó máa kojú, kékeré àti ńlá. Àwọn èèyàn ma já ọ kulẹ̀. Wọ́n máa mú ayé sú ọ. Bẹ́ẹ̀ni ìdiwọ́ yóò máa yọjú lọ́nà rẹ. Lọ́nà kan tàbí òmíràn, gbogbo ìpòrúru inú ayé yóò ma sún mọ́ ọ si lójojúmọ́. Nígbà tí o bá ṣe àpopọ̀ gbogbo ìdàrúdàpọ̀ ayé yí pẹ̀lú ìmò tara-ẹni-nìkan ti ẹ̀ṣẹ̀, ṣe ni o máa ṣe kòńgẹ́ àdììtú ńlá, àmọ́ tó bá sàn díẹ̀ o máa kojú ìgbésí-ayé àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn.

Bíbélì kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìkùnsínú àti ìjánúmọ́lẹ̀. Nínú Diutarónómì 1, Mósè ṣe àlàyé bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ní ìkùnsínú nípa ìgbésí-ayé wọn, nínú ìkùnsínú yí ni wọ́n ti ń bẹnu-àtẹ́ lu oore àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Ìwòye tí Ọlọ́run wá ṣe ni wípé nípasẹ̀ ìkùnsínú yìí àwọn èèyàn wọ̀nyí ti kọ̀yìn sí òhun; wọ́n ń fi hàn wípé àwọn kò ṣe tán láti ṣe ohun tí Ó pè wọn tí ó sì tún ró wọn lágbára láti ṣe. Ìdùnnú tàbí ìkùnsínú ọkàn rẹ ni yóò darí ìwúrí rẹ láti jẹ́rìí Ọlọ́run àti láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.

Ìkùnsínú yóò mú ọ gbàgbé ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Yóò mú ojú rẹ di sí ìwàláàyè Rẹ̀. Yóò mú ọ kọ̀yìn sí ẹwà àwọn ìlérí rẹ̀. Yóò mú kí a fojú fo ẹwà ìṣẹ̀dá Rẹ̀ tó tàn kárí ayé. Yóò máa yiri ire, ìṣòótọ́, àti ìfẹ́ Rẹ̀ wò. Yóò ma bèrè bóyá Ọlọ́run tilẹ̀ wà lókè bóyá ó kọbiara. Bí o bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ipá tí ó ní lóríi gbogbo ìṣẹ̀dá, o máa padà wá gbà wípé gbogbo ìkùnsínú rẹ, sí Ọlọ́run ni. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ti rí, ó rọrùn láti máa kùn sínú. Ó rọrùn láti gbàgbé ore ojojúmọ́ tí à ń rí gbà. Bí ó ti rọrùn fúnwa láti máa ṣe ìkùnsínú yí ni ìdí míràn pàtàkì tí a fi nílò ìdáríjì àti ore-ọ̀fẹ́ Jésù, ẹni tó kú fúnwa láì kùn sínú.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6Ọjọ́ 8

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/