Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 10 nínú 12

Kò sí ohun tí o lè ṣe láti fi jèrè ojú-rere Ọlọ́run. O ní láti gba èyí, kí o sì máa rántí rẹ̀. O kò lè jẹ́ olódodo tó láti tẹ́ ìlànà ìjẹ̀mímọ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Àwọn ẹ̀rò rẹ ò lè jẹ́ mímọ́ tó. Àwọn ìfẹ́ rẹ ò lè jẹ́ mímọ́ tó. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ò lè jẹ́ mímọ́ tó. Àwọn ìṣe rẹ ò lè gbé Ọlọ́run ga tó. Òdiwọ̀n náà ti ga jù fún ìwọ àti èmi láti dé. Kò sí àyàfi ẹnìkan. Gbogbo wa là ń gbé lábẹ́ òfin àti ìpalára ẹ̀ṣẹ̀ kan náà. A fé láti gbéraga ju láti wà ní ìrẹ̀lẹ̀. A fé láti bọ̀rísà ju ká sin Ọlọ́run. A fé láti bá omolàkejì wa já ju kí a fẹ́ràn wọn. Owú jíjẹ yá wa l'ára ju ìtẹ́lọ́rùn. Olè ni gbogbo wa l'ọ́nà kan tàbí òmíràn. A máa ń ṣ'ojú kòkòrò àwọn ohun ẹlòmíràn. Ó yá wa l'ára láti yí òtítọ́ dípò ká sọ bí ó ti rí. À ń fa ni lulè pèlú àwọn ọ̀rọ̀ wa ju bí a ṣe ń fi wọ́n gbé ẹlòmíràn ga. Ojoojúmọ́ ni á ń rí ẹ̀rí wípé a kò lè dé òṣùwọ̀n tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀.

Èyí ló kàgbà gbogbo rẹ̀: "Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Rẹ̀" (Rom. 3:20). Báwo ni èyí ṣe jẹ́ òtítọ́? Òtítọ́ ni torí wípé "gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run" (Rom. 3:23). Èdè náà bá gbogbo ènìyàn wi; kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Èyí ni òtítọ́ tí gbogbo ènìyàn ní láti gbà sínú ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n ìròyìn tí ó nira láti gbà yìí ni ọ̀nà láti má kórira ara ẹni, òun sì ni ọ̀nà ìrètí àti ayọ̀ ayérayé. Ìgbà tí o bá gba ẹni tí o jẹ́ àti àwọn ohun tí o kò lè ṣe ni ó ma bẹ̀rẹ̀ síí yé ọ ìdí láti ní ẹ̀bùn Ọlọ́run. É jẹ́ kí a mú ìròyìn méjèèjì náà papọ̀, bí Pọọlù ṣe ṣe ní Romu 3. Ó kọ wípé, "gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run," àmọ́ èyí kìí ṣe òpin ìtàn náà. Ó tẹ̀síwájú láti sọ wípé àwa tí a "dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀" (vv. 23–25).

Ètùtù tí Jésù ṣe pẹ̀tù sí ìbínú Ọlọ́run, ó sì là'jà láàrin Ọlọ́run àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Ọlọ́run kórira ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, ọ̀nà kan ṣoṣo tí àwa ẹlẹṣẹ̀ lè ní ìbáṣepọ̀ pẹlú Rẹ ni bí Jésù ṣe fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa. O kò ní láti gbọ́ràn láti rí ojú-rere Ọlọ́run; Krístì ti gba ojú-rere Ọlọ́run fún ẹ. Ìdí èyí ni ìgbọ́ràn rẹ kò ṣe jẹ́ ẹ̀san ẹ̀rù, ṣùgbọ́n orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run tí ó pàdé rẹ n'íbi tí o wà, tí ó sì ṣe fún ọ ohun tí o kò lè ṣe fún ara rẹ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 9Ọjọ́ 11

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/