Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ
L'òtítọ́ ni wípé ọkàn l'ára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ga jùlọ nínú àwọn ìbáṣepọ̀ wa ni ẹ̀ṣẹ̀ ìgbàgbé. Ẹ wo òwe Jésù yìí:
Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún tálẹ́ǹtì. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà. Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. Ó bẹ̀bẹ̀ pé, "Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ." Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, "San gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀." Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, "Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ." Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, "Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?” (Matt. 18:23–33)
Gbogbo wa ni ìgbàgbé lè ṣẹlẹ̀ sí. A lè gbàgbé ìwọ̀n ìfẹ́ àti àánú ńlá tí a ti fi hàn sí wa. A lè gbàgbé wípé kò sí bí a ṣe le l'ẹ̀tọ́ sí àwọn ohun tí ó dára jùlọ nínú ayé wa; wọ́n jẹ́ tiwa nípa ore-ọ̀fẹ́ nìkan. Ibi tí ìṣòro wà l'èyí: ìwọ̀n bí a bá se gbàgbé ore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi hàn wá, ìwọ̀n náà ni a máa kọ̀ láti fi ore-ọ̀fẹ́ hàn sí ẹlòmíràn. Ìwọ̀n bí a bá se gbàgbé ìdáríjí tí a rí gbà, ìwọ̀n náà ni a máa kọ̀ láti dáríjì ẹlòmíràn ní àgbègbè wa. Bí o bá kọ̀ láti ní ọkàn ọpẹ́ nítorí ìfẹ́ tí a rí gbà l'ọ̀fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yíò ṣe nira láti dáríjì ẹlòmíràn bí ó ti yẹ.
L'òtítọ́ ni wípé kò sí ẹni tí ọ̀rọ̀ ore-ọ̀fẹ́ yé tí ó sì fifún ni tó ẹni tí ó mọ̀ wípé òun nílò rẹ̀ tikalararẹ, àti wípé a ti pèsè rẹ̀ lẹkunrẹrẹ láti ọwọ Ọlọ́run àánú. Ó fún ohun tí òun kò lè rí gbà; kí lódé nígbà náà, tí a fi kẹ̀hìn sí àwọn ẹlòmíràn títí di ìgbà tí wọ́n bá kún òṣùwọ̀n tí a gbé kalẹ̀? Ìpè láti dáríjì ṣí ojú wa sí ìní àwa náà fún ìdáríjí. Ìpè sí ore-ọ̀fẹ́ fi hàn bi àwa náà ṣe nílò ore-ọ̀fẹ́. Ìpè sí ìdáríjí jẹ́ ìpè sí ìrántí àti láti dúpẹ́. Nígbà tí o bá rántí bí ìwọ náà ti kùnà, wà á láàánú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n kùnà náà, wà á sì fẹ́ fún wọn ní ore-ọ̀fẹ́ tí ó jẹ́ ìrètí re nìkan. Kí Ọlọ́run fún wa ní ore-ọ̀fẹ́ láti rántí ati ìyọ̀nda láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ǹkan tí àwa náà ti rí gbà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.
More