Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 9 nínú 12

Bí mo ṣe ń kọ nípa àwọn ààmì ìfẹ́ gidi "òtítọ́, ìrẹ̀lẹ̀, ìdùnnú àti ìforítì", ọkàn mí kún fún ìbànújẹ́ àti ìdálẹ́jọ́. Mo rò nínú ara mi wípé, "Ìfẹ́ mi máa ń kùnà láti jẹ́ òtítọ́ nígbà míràn." Ìfẹ́ òtítọ́ ni mọ̀ ń s'ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ dédé, tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lẹ́, tí kò ní ìkúndùn láti yà bárá ní ọ̀nà míràn. Ó ṣe ni l'áàánú wípé àìṣe dédé wà nínú ìfẹ́ mi. Nígbà tí ẹnìkan bá kọ̀ láti gbà ète témi, nígbà tí ẹnìkan bá dúró s'áàrín èmi àti ẹ̀tọ́ mi, nígbà tí ó bá di dandan fún mi láti dúró de ǹkan tàbí ẹnìkan, tàbí nígbà tí ẹnìkan bá gba ohun tí mo gbàgbọ́ wípé ó tọ́ sí òdì, ó máa ń jẹ́ àdánwò nlá fún mi láti dáhùn pẹ̀lú ìfẹ́.

Ọ̀rọ̀ kejì, ìrẹ̀lẹ̀, s'àlàyé ìdí tí mo fí ń hùwà. Mí ò tíì di ẹni ìrẹ̀lẹ̀. Mo sì máa ń fẹ́ kí ayé dá lé orí àwọn èrò mi, ìfẹ́ mi àti àwọn ìkùnsínú mi. Ó sì máa ń jẹ́ àdánwò fún mi láti wo bí ọjọ́ ṣe dára tó pẹ̀lú bí ó ṣe tẹ́ mi l'ọ́rùn dípò bí ó ṣe tẹ́ Ọlọ́run l'ọ́rùn àti bóyá mo n'ífẹ̀ẹ́ ẹlòmíràn, bíi wípé èmi ni mo ni ayé mi, Láì rántí wípé a ti rà mí ní iye kan. Gbogbo èyí á jẹ́ kí ìfẹ́ di ẹrù, dípò ayọ̀, èyí tíí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìsàpèjúwe kẹta. Òótọ ni wípé nígbà tí o bá ń gbé fún ara ẹ nìkan, ìpè láti féràn ẹlòmíràn á di ẹrù fún ọ.

Ọ̀rọ̀ ìparí tọ́ wa sí òṣùwọ̀n ìfẹ́ tí ó ga, tí ò sì le jù: sùúrù. Ìfẹ́ tí kò jẹ́ olódodo jẹ́ ìfẹ́ tí kò ní iye. Ìfẹ́ tí ń yi bí ọjọ́ kìí ṣe ìfẹ́ rárá. Irú èyí á máa ba ǹkan jẹ́ dípò kí ó tún n ṣe. Nítorí náà ni ìfẹ́ òdodo àti àìlópin Ọlọ́run ṣe jẹ́ ìtùnú nlá àti ohun ìwúrí fún wa.

Ìbéèrè níyì, "níbo ni mo ti máa rí irú ìfẹ́ yìí?" Mọ̀ dájú wípé kìí ṣe nípa sísọ fún ara ẹ̀ wípé o lè ṣe ju ti tẹ́lẹ̀ lo. Tí ò bá lágbára láti yí ayé rẹ padà, àgbélèbú Jésù Kristi jẹ̀ lásán. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí mo lè fi bọ́ l'ọ́wọ ìfẹ́ ara mi, kí n sì bẹ̀rẹ̀ síí máa fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn ni wípé kí a dá ìfẹ́ òmìnira, alágbára àti àìlópin sínú mi.  Ìwọ̀n ìgbà tí mo bá ń s'ọpẹ́ fún ìfẹ́ yìí, bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ṣe máa kún inú mi láti fi hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí mo bá fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn pẹ̀lú ìyọ̀nda nìkan ni ìrètí wà wípé èmi náà yíò rí ìfẹ́ gbà.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 8Ọjọ́ 10

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/