Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 1 nínú 12

Ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ṣe oun méjì pàtó fún gbogbo wa. Àkọ́kọ́, ó máa jẹ́ kí a fi ara wa sí àárín ìgbésí ayé wa, kí ó baà lè dà bíi wípé oun gbogbo wà fún wa. Èyí á jẹ́ kí a máa ronú àwọn ìfẹ wa, àwọn àìní wa, àwọn ìkùnsínú wa, èyí tí á jẹ́ kí a rí àwọn oun tí a kò ní dípò àwọn oun tí a ti fún wa. Èyí náà yí ó sì mú wa máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn, fífi àwọn ohun tí a ní wé ohun tí àwọn ẹlòmíràn ní. Ayé ainitelorun àti owú ni. Owú á sì máa mọ t'ara rẹ̀ nikan nígbà gbogbo.

Ohun kejì tí ó dà bíi rẹ̀ tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ṣe fún wa ni wípé á jẹ́ kí a máa wo àwọn ǹkan lódì lódì. Nítorí náà, a máa máa wo ìṣẹ̀dá fún ìrètí, ìyè, àláfíà, ìsinmi, ìtẹ́lọ́rùn, ìdánimọ̀, ìtunmọ̀, ìdí àti ìwúrí láti tẹ̀síwájú. Ìṣòro ibè ni wípé ìṣẹ̀dá kò lè fún ọ ní àwọn ǹkan wọ̀nyí. A kò dá ìṣẹ̀dá láti tẹ́ ọkàn rẹ lọ́rùn. Ìṣẹ̀dá yẹ kí ó tàn ọ́ lọ́nà sí Ẹni kan ṣoṣo tí ó lè tẹ́ ọkàn rẹ lọ́rùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni á jí lónìí tí wọ́n à sì béèrè lọ́wọ́ ìṣẹ̀dá fún ìgbàlà, ohun tí Ọlọ́run nìkan lè fún ni.

“Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ? Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.  Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi, ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi, ati ìpín mi títí lae.” (Orin Dáfídì 73:25–26). Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ eni tí ó ti mo àṣírí ìtẹ́lọ́rùn. Nígbà tí o bá wà ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú Afifunni, nítorí o ti rí ìyè tí ò ń wá nínú Rẹ̀, o di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìwádìí apanirun ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń wá lónìí. Bẹ́ẹ̀ni, òtítọ́ ni wípé ọkàn rẹ yíò sinmi nígbà tí o bá rí isinmi nínú Rẹ̀.

Èyí ni ọ̀kan l'ára àwọn èso ore-ọ̀fẹ́ tí ó l'ẹ́wà jù lọ - ọkàn tí ó ní ìtẹ́lọ́rùn, tí ó ń sìn jù bibeere, tí ó ní ayọ̀ ìm'oore ju àníyàn. Ore-ọ̀fẹ́ nìkan ló lè mú irú ayé àláfíà yí wáyé fún ọ̀kànkan wa. Ǹjẹ́ o kò ní gba ore-ọ̀fẹ́ yìí lónìí?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/