Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ
Owú mọ ti ara rẹ̀ nìkan, ó sì gbe òdodo ara-ẹni ga. Á fi ọ́ sí àárín ayé rẹ. Á sọ ohun tí ó yẹ ọ́, àti ohun tí kò tọ́ sí ọ. Owú á máa retí, á sì máa béèrè. Á sọ fún ọ wípé o jẹ́ ohun tí o kò jẹ́, àti ohun tó tọ́ sí ọ àmọ́ tí kò jẹ́ tìrẹ ní tòótọ́. Owú ò lè yọ̀ nítorí ìbùkún ẹlòmíràn torí á sọ fún ọ wípé ìwọ yẹ ju ẹni náà. Owú á sọ fún ọ wípé ó yẹ́ kí ọ jo'gún ohun tí o kò lè jo'gún láíláí. Ayé owú ò lè bá ayé ore-ọ̀fẹ́ rìn. Owú á gbàgbé ẹni tí ọ jẹ́, eni tí Ọlọ́run jẹ́, ó sì wà ní ìríjú nípa ohun tí ayé n ṣe.
Síbẹ̀síbẹ̀, bí a tilẹ̀ ti sọ gbogbo èyí, òtítọ́ ni wípé gbogbo wa là ń jìjàkadì pẹ̀lú owú ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, nígbà kan tàbí òmíràn. A máa jowú torí wípé ẹnìkejì wa ṣe àṣeyọrí nínú ohun tí a kò tíì lè ṣe. Owú fẹ́ kí ìgbéyàwó wa ládùn bíi ti àwọn ọ̀rẹ́ wa ní ilé ìjósìn. Iṣẹ́ òòjọ́ wa kò tẹ́ wa lọ́rùn mọ́ nítorí ẹnìkejì tó ní iṣẹ́ tó ń yege. A máa jowú ìpéjọpò ẹlòmíràn nítorí wípé ó ń ṣe rere ju tiwa lọ. A fé máa jẹun bíi lágbájá kí a sì má sanra. Ẹni tí ó ga fẹ́ kúrú, ẹni tí ó kúrú fẹ́ ga. Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀rọ̀ yìí bá gbogbo ènìyàn wí nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ bá gbogbo ènìyàn. Owú ní gbòǹgbò rẹ̀ nínú ìmọ́ t'ara ẹni ẹ̀ṣẹ̀ (wo 2 Kor. 5:14–15). Nítorí wípé owú á máa béèrè ní gbogbo ìgbà, à máa gbé dídára Ọlọ́run lè ọ̀ṣùwọ̀n ìdáhùn Rẹ̀ sí àwọn ẹ̀bẹ̀ ádùrá rẹ. Nígbà tí o bá béèrè síi ṣe iyè méjì dídára Ọlọ́run, o kò ní fẹ́ béèrè ohunkóhun l'ówó Rẹ̀. Owú jẹ́ àjálù èmí.
Ore-ọ̀fẹ́ á rán ọ létí wípé kò sí ohunkóhun tó tọ́ sí ọ. Àmọ́ á kọ́ ọ pẹ̀lú òtítọ́ wípé Ọlọ́run jẹ́ onífẹ́, olóre-ọ̀fẹ́, aláànú àti wípé Ó fún wa ní ohun gbogbo tí kò tọ́ sí wa. Ore-ọ̀fẹ́ á rán wa létí wípé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run àti wípé kìí ṣe àṣìṣe - Ó máa ń fún oníkálukú wa ní ohun tí a nílò ní pàtó.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.
More