Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 5 nínú 12

Ó jẹ́ ọ̀kan nínú ètò ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Ọlọ́run, sugbon a kìí ṣe bí ẹni wípé a ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Gbogbo wa máa ń  sọ wípé kì í ṣe gbogbo ohùn tí ó wà ní yí. A máa ń sọ wípé ayé míràn tún wà lẹ́yìn èyí tí a wà nínú rẹ̀ yí bá dópin. Iṣẹ́ ẹ̀kọ́ wa nípa Ọlọ́run ní ìrètí ọ̀run titun àti ayé títún tí ó ń bọ̀. Ṣùgbọ́n a máa ń ṣábà gbé pẹ̀lú àníyàn àti ìdarí tí ó máa ń wà nígbà tí a bá gbàgbọ́ wípé àkókò yí nìkan ni a ní.

Òdodo ọ̀rọ̀ ibẹ̀ ní yìí: bí ó kó bá fi ojú-inú rẹ tẹjú mọ́ Párádísè tí ń bọ̀, ó máa fẹ́ sọ ayé òsì àti ẹ̀ṣẹ̀ yíì di Párádísè tí kò lè jẹ́ lailai. Nínú ọkàn gbogbo ẹ̀dá alààyè ni òùngbẹ Párádísè. Ẹkùn Párádísè wà nínu ẹkún tí Ọmọ-ọwọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ń ṣún. Ẹkùn tí Ọmọ ilé-ìwé tí a tanù lórí pápá ìṣeré ń ṣún ni èyí tí ó ń fẹ́ nawọ́ gan Párádísè. Ìrora tí ẹni tí ó dá wà láìsí ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí ní ni  ìrora ẹni tí ó ń fojú sọ́nà fún Párádísè. Ìpalára tí ó wà nínú títú ìgbéyàwó tọkọtaya ká ní ìpalára tí ó ń sọkun un Párádísè. Ìfajúro tí baba arúgbó ń ní ìmọ̀lára rẹ jẹ Ìfajúro ẹni tí ó ń fojú sónà fún Párádísè. Gbogbo wa ni ifoju sónà yíì, kódà ní ìgbà tí a ko ba ni ìmọ̀lára rẹ náà, nítorí wípé Ẹlẹ́dàá wá ló fi síbẹ̀. Ó ti fi ayérayé sínú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa(Ìwé Oníwàásù 3:11). Ẹkùn wá pọ̀ ju kíké ìrora; ó tún jẹ́ ẹkùn ìfojúsọ́nà fun ohun tí ó dára tí ó sì pọ̀ jú ohun tí a lè rí ìrírí rẹ ni àyè yí.

Bí ó bá gbàgbé èyí, o máa ṣiṣẹ́ kíkan kíkan láti yí àkókò yí padà sí Párádísè tí kò lè jẹ́. Ìgbéyàwó rẹ kò ní di Párádísè.  Iṣẹ́ rẹ ko ni jẹ́ párádísè tí ó ń fojú sónà fún. Àwon ọ̀rẹ́ rẹ kò ní je párádísè tí ònfa rẹ̀ ń fà ọkàn rẹ. Ayé tí ó yí ọ ká kò ní dà bíi párádísè. Àwọn ọmọ rẹ kò ní jọ̀wọ́ párádísè fún ọ. Kódà, ìjọ rẹ kò ní pójú òṣùwọ̀n párádísè. Bí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, a ti ṣe ìlérí párádísè fún ọ, ṣùgbọ́n kò ní jẹ́ nísinsìnyí. Gbogbo ohun tí ó bá já ọ kulẹ̀ nísinsìnyí wá níbẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní yìí, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún párádísè tí ó ń bọ̀. Àwọn àlá tí ó kú wá láti rán ọ létí wípé ayé yìí kìí ṣé párádísè. Òdòdó tí ó ń ran ọ́ létí pé ibí kìí ṣe párádísè. Ẹsẹ ti o n fa ìfẹ́ ọkàn rẹ gbọ́dọ̀ rán ọ létí wípé párádísè kọ́ ni yìí. Àwọn àìsàn tí ó ràn ọ́ wá níbẹ̀ láti rán ọ leti wípé párádísè kọ́ ni yìí. Máa gbé nínú ìrètí nítorí wípé dájúdájú párádísè ń bọ̀,  kí ó sì yee béèrè pé kí àyè sì ṣubú yìí di párádísè tí kò leè jẹ́ lailai.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/