Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 8 nínú 12

Ó jẹ́ ọ̀kan l'ára ohun tí gbogbo wa máa ń ṣe. A máa ń wá ìyè nínú àwọn ohun tí kò tọ́. A máa ń wo ayé tí a dá láti fún wa ní ìyè. Gbogbo wa là ń gbé "kání wípé" wa kiri. "Kání wípé mo ti ní ìyàwó, inú mi ìbà dùn." "Kání wípé mo lè rí iṣẹ́ yen gbà, ọkàn mi ìbá balẹ̀." "Kání wípé a lè ta ilé yen, ń kò rò wípé má a fẹ́ ohun míràn." "Kání wípé ìgbéyàwó mi tòrò, ǹ bá wà dáadáa." "Kání wtipe àwọn ọmọ mi ṣe rere, ayọ̀ mi ìbá kún." "Kání wípé mo lè ṣe ____, mi ò ní fẹ́ ohun míràn." "Kání wípé ètò ìṣúná mi gún régérégé, mi ò ní s'àròyé mọ́."

Ohunkóhun tí o bá ń wá ní ìdákejì "kání wípé" rẹ ni ìbí tí o ti ń wá ìyè, àláfíà, ayọ̀, ìrètí àti ìtẹ́lọ́rùn ọkàn pípẹ́. Ìṣòro ibè ni wípé wà á tẹ̀síwájú láti máa ná owo l'órí ǹkan tí ó lè di ofò, àti láti máa ṣiṣẹ́, torí o fẹ́ gba ǹkan tí kò lè tẹ́ ọ lọ́rùn. Àṣìṣe èmi nlá ni, èyí tíí mú ènìyàn jẹ gbèsè oríṣìíríṣìí láì sí ìtẹ́lọ́rùn ọkàn. Kíni ìdí èyí? Ayé ò lè jẹ́ olùgbàlà rẹ láì. Ayé tí a dá pẹ̀lú gbogbo ohun rírí, ariwo, ìrírí àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ kò ní agbára láti mú ọkàn rẹ sinmi. Ọlọ́run dá ayé yìí láti jẹ́ ìka nlá tti yíò darí rẹ sí ibi tí ìtẹ́lọ́rùn àti ìsinmi wà. Ọkàn rẹ ò sì le è sinmi àyàfi tí ó bá sinmi nínú Ọlọ́run nìkan.

Nítorí náà, Jesu wípé: "Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́" (Luku 12:33). Kíni ohun tí o máa gb'ọ́kàn lé lónìí ní ìrètí wípé yíò fún ọ ní ìyè? Níbo ni o ti máa wá àláfíà àti ìsinmi ọkàn? Kíni o máa wá láti fún ọ ní ìrètí, ìgboyà àti ìdí láti tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò rẹ? Níbo nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ni o máa gbérò láti wá ohun tí Asèdá nìkan lè fún ọ? Oúnjẹ wo lo máa rà lónìí tí kò ní pa ebi èmi rẹ?

Kíni ìdí tí o fi máa wo ìṣẹ̀dá láti fún ọ ní ohun tí a ti fún ọ nínú Kristi? Kíni ìdí tí o fi máa fẹ́ kí ayé ẹ̀ṣẹ̀ yìí jẹ́ olùgbàlà rẹ nígbà tí Jésù ti wá gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ láti fún ọ ní ohun gbogbo tí o nílò nínú ore-ọ̀fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Rẹ̀?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 7Ọjọ́ 9

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/