Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ
Ìbá wù mi láti lè sọ wípé mo máa ń ni ìtẹ́lọ́rùn ní gbogbo ìgbà. Ìbá wù mi láti lè sọ wípé ń ó kí n ṣ'àròyé. Ìbá wù mi láti lè sọ wípé ó fi ìgbà kankan féràn oun ti o jẹ́ ti ẹlòmíràn. Ìbá wù mi láti lè sọ wípé mi o fi ìgbà kankan jowú ìgbé àyè ẹlòmíràn. Ìbá wù mi láti lè sọ wípé ń ó fi ìgbà kankan rò wípé e Ọlọ́run fi ẹ̀tọ́ mi fun ẹlòmíràn. Ìbá wù mi láti lè sọ wípé mo ń ṣe dáadáa nínu kíka ìbùkún mi ju ṣíṣe àyẹ̀wo oun ti ń ko ni lọ. Ìbá wù mi láti lè sọ wípé ebi tí ó ń pá mi fún ohun ìní kò pọ tó bayi. Ìbá wù mi ki ọkàn mi jàjà ni ìtẹ́lọ́rùn.
Gbobgbo ǹkan wọ̀nyí ló wù mí láti ní nítorípé wọn kìí ṣe òtítọ́ pátápátá nípa mí. Ìlara ṣì ń farapamọ́ sínú ọkàn mi. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tó dúdú birimù, tí ó ṣì ń gbé ibẹ̀. Èéṣe tí Bíbélì fi lòdì sí ìlara? Òun rèé: nígbàtí ìlara bá ń jọba nínú ọkàn rẹ, ìfẹ́ Ọlọ́run kò lè ráyè. Ẹ jẹ́ k'a ro oun tí ìlara ń ṣé. O lérò wípé o ní ẹ̀tọ́ si ìbùkún tí o kò l'ẹ́tọ̀ sí. Nígbàtí ìlara ba jẹ́ olùdarí ọkàn rẹ, ìwà "mo l'ẹ́tọ̀ọ́" ni máa ń rọ́pò ìṣesìi "alábùkún fún ní mi". Ìlara jẹ́ ìmọtaraẹni nìkan tó ga jù lọ. Ìlara màá ń gbe ọ si àárín ayé. Yóò wá mú gbogbo ǹkan jẹ́ nípa tìrẹ nìkan. Yóò jẹ́ kí o ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé láti ìrísi ohun tí ò ń fẹ́, tí o nílò, àti ti ò ní ìmọ̀lára rẹ̀.
Ohùn tí ó bani lọ́kàn jẹ́ ní wípé, ìlara a máa ṣokùnfà ìyíri wò dídára, ìṣòtọítọ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Ìlara máa ń f'ẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò mọ ohùn tí ó ń ṣe, tàbí pé kò ṣe òtítọ́ si ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ. Nígbà tí ó bá dá ọ lójú wípé ìbùkún ẹlòmíràn jẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ, o kò ní ọ̀ràn pẹ̀lú onítọ̀hún nìkan, ó ní ọ̀ràn pẹ̀lú Ọlọ́run. Nígbà ti o bá ti ń yiri dídára Ọlọ́run wò, ó máa kọ lílọ sí ọ̀dọ rẹ fún ìrànwọ́ sílẹ̀. Kíni ìdí èyí? Nítorípé o kò ní béèrè fún ìrànwọ́ lọ́dọ̀ eni tí ìwọ ń ṣiyèméjì sí.
Ìlara máa ńṣe ohun míràn tí ó léwu nípa tí ẹ̀mí. A máa ṣèbí wípé òhun ní ìmọ̀ tí ẹnì kankan kò ní. Ìlara ò wá tán síbẹ̀ nípa mímọ ọmọ-làkejì rẹ̀, ó lè tún ṣèbí wípé òun ní òye ohun tí ó dára ju bi Ọlọ́run ti mọ̀ lọ. Síwájú síi, ìlara a máa mú ni gbàgbé oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó ń yani lẹ́nu, tí ó ń kóni yọ, tí ó ń rani padà, tí ó ń fúnni lágbára, tí ó sì ń gbani là. Ṣíṣe ìṣírò ohun tí o kò ní yóò wá jọba lọ́kàn rẹ débi wípé ìbùkún oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run bàntàbànta - ìbùkún tí o kò lè ṣíṣe fún, tí o kò yẹ fún, tí kò sì tọ́ sí ọ - á wá di ohun àìkọbiarasí tí a kò sì ṣe àjọyọ̀ rẹ̀. Bákan náà, nítorí wípé ìlara máa ń tejúmọ́ ohun tí ó ń fẹ́ ju ìgbé ayé tí Ọlọ́run pè ọ́ sí lọ, a máa mú ọkàn rẹ kúrò nínú ṣíṣe àkíyèsí òfin àti ìkìlọ̀ Ọlọ́run, yóò sì fi ọ́ ṣílẹ̀ nínú ipò tí ó léwu. Ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo sí ìlara ni oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó ń gbani là - oore ọ̀fẹ́ tí ó ń sọ ẹlẹ́ṣẹ̀, tí kò mọ̀ ju tara rẹ̀ nìkan di olùjọsìn tó l'áyọ̀ àti ítẹ̀lọ́rùn nínú Ọlọ́run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.
More