Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì nípa Ìdúpẹ́ Látọwọ́ Paul TrippÀpẹrẹ

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ọjọ́ 3 nínú 12

Ẹ̀mí àti ìwọ nílò láti sọ ọ́ fún ara wa léraléra. A nílò láti wo inú dígí kí a sì ṣe ìjẹ́wọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ojúṣe àràárọ̀ wa. Ohun tí a ní láti sọ nìyí: “N kò tíì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ẹ̀kọ́-gíga ti ore-ọ̀fẹ́.” Ó máa ń rọrùn fúnwa láti ṣe àwáwí ìṣòdodo asán wa:

“Ìfẹ́kúùfẹ́ kọ́ni ìyẹn. Mo kàn ń mọ rírì ẹwàa rẹ̀ ni."

“Ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn kọ́ nìyẹn o. Mo kàn ní kí n ṣe àlàyé kókó àdúrà náà síwájú síi ni.”

“Inú kò bí mi sí àwọn ọmọ mi. Mo kàn ń ṣiṣẹ́ wòlíì ni. ‘Báyìí ni lolúwa wí . . .’”

“Kìí ṣe wípé agbára ń gùn mí. Rárá, mo kàn ń lo àwọn àmúyẹ adarí tí Ọlọ́run fi fúnmi ni.”

“Èmi kìí ṣe ìkà ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ni n kò ní ahun. Mo kàn ń gbìyànjú láti jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere nípa ríràgàbò ohun ìní tí Ọlọ́run fúnmi ni.”

“Mi ò dẹ̀ wá gbéra-ga o. Mo kàn wòye wípé ẹnìkan ní láti ṣe agbátẹrù ìtàkùrọ̀sọ náà ni.”

“kìí ṣe irọ́ taratara ni ǹkan tí mo sọ. Mo kàn gba ọ̀nà àrà gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ ni.”

Ó fẹ́rẹ̀ lè jẹ́ gbogbo wa ló ma ń rò wípé a mọ́ ju bí a ti rí lọ. Kìí yá wa lára láti gbà wípé a sì nílò ore-ọ̀fẹ̀ Ọlọ́run láti gbà wá. Bẹ́ẹ̀ni a kìí fẹ́ gbà wípé a nílò láti gba oníkálukú kúrò lọ́wọ́ ogun ara ẹni! Nígbà tí o bá ńṣe àwáwí fún ìṣòdodo asán rẹ, ní ìgbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́lẹ̀, nípasẹ̀ èyí o ti kùnà láti ṣe àwárí ore-ọ̀fẹ́ ńlá èyí tí í ṣe ìrètí kan ṣoṣo tí o ní. Ẹlẹ́ṣẹ̀ nìkan ni ó lè mọ rírì ore-ọ̀fẹ́. Àwọn òtòṣì nìkan ló lè mọ rírì àwọn ìṣúra ọrọ̀ ire Ọlọ́run.

Àwọn tó mọ rírì ìwòsàn ti ẹ̀mí látọwọ́ Olùwòsàn Ńláa nì àwọn tó sì gbà wípé àwọn ń jìjàkadì pẹ̀lú àìsàn tẹ̀mí - ẹ̀ṣẹ̀. Ǹkan tó máa ń bomi ọgbẹ́ sí Ọlọ́run lọ́kàn ni nígbà tí a bá ké halleluyah lọ́jọ́ ìjọsìn tí a sì wá kọ ore-ọ̀fẹ́ ṣílẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀. Kojú òtítọ́ náà lónìí wípé o kò tíì dàgbà ju ẹni tí ń nílò ore-ọ̀fẹ́ lọ, kò sí bí o ti ní ìmọ̀ sí tàbí dàgbà tó, títí di ọjọ́ tí ìwọ yóò sọdá sí òdì-kejì níbi tí kò ti sí làálàá, nítorí a óò mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sópin (wo Fílípì 3:12–16). Ọ̀nà tí a fi lè yọ̀ nínú ore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run fi fúnwa ni láti gbà wípé a nílòo rẹ̀ gidi.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Paul Tripp's Daily Thanksgiving Devotional

Ìdúpẹ́ jẹ́ àkókò láti rántí gbogbo ohun rere tí ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ fifún wa. Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan hílàhílo ti àkókò lè dí wa lọ́wọ́ àti fi ààyè sílẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́run fún àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ètò agbani ní ìyànjú láti ọwọ́ Paul David Tripp, àwọn ètò kúkúrú yi gba ìṣẹ́jú màrún péré láti kà, ṣùgbọ́n wọn yíò gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe àṣàrò lóríi àánú ọlọ́run jákèjádò ọjọ́ òní.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Crossway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.crossway.org/books/new-morning-mercies-hcj/