Ìrìn àjò lo si Ìbùje EranÀpẹrẹ

Journey To The Manger

Ọjọ́ 11 nínú 70

Ìtàn Ìràpadà

Ìwé Matiu bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìran ìdílé tí ó ṣe kókó jùlọ nínú ìtàn àgbáyé: ìran Jésù Krístì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìròyìn Matiu kìí ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́, ó tó láti fún wa ní àwòrán alágbára ti ìdílé Jésù.

Àwọn ọmọ Júù á ti mọ àwọn orúkọ jànkàn jànkàn wọ̀nyí. Matiu fẹ́ t'ẹnu mọ́-on wípé n'ípasẹ̀ Èmí Mímo ni a bí Jésù, sínú ìdílé ènìyàn tí ó ní ìpèníjà tirẹ̀, àmọ́ tí Ọlọ́run bá ṣe pọ̀ nínú ìtàn. Jésù jáde láàrin ìtàn àwọn akọni, ènìyàn lásán, aṣáájú, àwọn tí ń sá àsálà fún èmí wọn, àwọn asẹ́wó tí a rà padà àti àwọn ọba tó kọ̀ láti ronú pìwàdà.

Àwọn orúkọ náà lè nira láti mọ̀ tàbí láti pé, ṣùgbọ́n láàrin wọn ni àwọn ìtàn ìfẹ́ àti agbára Ọlọ́run wà, bí Ó ṣe ń hun ìràpadà pẹ̀lú òwú àìníye títí tí ó fi dé ọ̀dọ̀ Jésù.

Iṣẹ́ ṣíṣe: Kọ àkójọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún ọ nínú ọdún yìí. Yin Olúwa fún ọ̀nà pàtó kánkan tí Ó ti tọ́jú rẹ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 10Ọjọ́ 12

Nípa Ìpèsè yìí

Journey To The Manger

Ní alẹ́ ìdákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ọdún 2000 sẹ́yìn, àwọn angẹli mu ìròyìn ìbí Olùgbàlà wá fún ẹgbẹ́ àwọn daran-daran kan níbi tí wọn ti ń da ẹran wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìròyìn náà, àwọn daran-daran wọ̀nyí fi ohun gbogbo sí'lẹ̀ láti wá ìkókó tí ó wà ní ibùjẹ ẹran ní Bẹtilẹhẹmu. Lẹ́yìn gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, ìpè yìí kò tíì yí padà. Ẹ̀ bá Dr. Charles Stanley rìn bí ó ṣe ń ràn yín l'ọ́wọ́ láti súnmọ́ Olùgbàlà, àti láti mú ọkàn yín le láti wá àyè láti sinmi nínú ìfẹ́ Bàbá ní àkókò yíì. 

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò visit: https://intouch.cc/yv18