Ìrìn àjò lo si Ìbùje EranÀpẹrẹ

Journey To The Manger

Ọjọ́ 13 nínú 70

Ète Rè tó Ga

Ó sábà máa ń jé àkókò ìjákulẹ̀ ńlá ni Olórun máa ń fún wa láǹfààní láti sàwárí ète Rè tó ga ju fún ayé wa.

Nígbà kan lèyín ìdánaàdéhùn ìgbéyàwó Màríà sí Jóséfù, Màríà wá sódó rè o gbé ìròyìn ti kò seé ronú kàn sókàn. Ó ti lóyún —àtipe ó so pé o jé àbájáde isé ìyanu ńlá. Okàn Jóséfù gbódò tí nímólarà fifó túútúú. Kò sí yíyàn tó dára—gbé obìnrin aláìsódodo ní ìyàwó àti fara dà ìdálẹ́bi tàbí dójú ti obìnrin tó bọ̀wọ̀ fún àti bìkítà fún láwùjò. Báwo ni Olórun se ni ohunkóhun láti se pèlú ìyípadà àwon ìsèlè oníkàyéfì?

Bí Jóséfù se gbìyànjú láti sùn ní alé náà, ángèlì wá láti so fún pé kó gbá Màríà gbó—àti tọkàn-tọkàn jé enìkejì pèlú è ní ìpè tó yàtò láti jé bàbá àti ìya ayé Omo Olórun. Jóséfù lè tí dáhùn pèlú àìgbágbó tàbí ìkorò. Síbè nípasè ìgbàgbó rè, Olórun sàseparí ète tí kò láfiwé tó ga tó má bú kún aráyé fún títí láé.

Isé Sisé: Lo àkókò nínú ojó rè láti kà ìwé ìtàn tó féràn jù lo sí omodé kan láyé rè.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 12Ọjọ́ 14

Nípa Ìpèsè yìí

Journey To The Manger

Ní alẹ́ ìdákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ọdún 2000 sẹ́yìn, àwọn angẹli mu ìròyìn ìbí Olùgbàlà wá fún ẹgbẹ́ àwọn daran-daran kan níbi tí wọn ti ń da ẹran wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìròyìn náà, àwọn daran-daran wọ̀nyí fi ohun gbogbo sí'lẹ̀ láti wá ìkókó tí ó wà ní ibùjẹ ẹran ní Bẹtilẹhẹmu. Lẹ́yìn gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, ìpè yìí kò tíì yí padà. Ẹ̀ bá Dr. Charles Stanley rìn bí ó ṣe ń ràn yín l'ọ́wọ́ láti súnmọ́ Olùgbàlà, àti láti mú ọkàn yín le láti wá àyè láti sinmi nínú ìfẹ́ Bàbá ní àkókò yíì. 

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò visit: https://intouch.cc/yv18