Ìrìn àjò lo si Ìbùje EranÀpẹrẹ
Ètò Ìràpadà Olórun
Nígbà tí Jésù wá sílẹ ayé, Àwọn èèyàn tí Rè wón kò mò O. Bí o tí lè jé pé a tí bukún àwọn Júù pèlú èrí lat'ọdọ awọn àlùfáà won àti ìtàn látojó pípé nípa ìtèsíwájú jíjẹ olódodo Olórun, síbè wón kò dà Mèsáyà tí a ń retí tipẹ́tipẹ́ mò. Won ṣàkóso pé Yóò wá àtii gbà wón là lówó àwọn aninilára ìṣèlú wọn, tó máa pa ṣinṣin òrìsà run àti ìgbèkùn ìṣàkóso Róòmù. O máa mú wa wọnú ìjọba Ọlọ́run. Nínú ọkàn won, ìyen túmọ sí titún fìdí àwọn ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì múlẹ̀ lọ́nà tí ó hàn gbangba àti agbára.
Àmó Jésù kò wá láti mú àkọsílẹ ná gbórò nípa pípa àwon Kèfèrí olórísà tí a tẹ́ńbẹ́lú. O wá láti mú wa wọnú ìjọba tí kìí ṣe tí ayé yìí —àti láti mú òtítọ Olórun àti iwájú Rè sínú ayé tó túká.
Báwo ní a ṣe yàtọ sí àwon tó pàdánù bíbò Ọba wọn nígbà tí ìgbéraga tí fò ojú wọn sí òtítọ tí ètò ìràpadà Olórun? Kí a dà bí àwọn díẹ̀ tí ojú èmí wọn sí sílẹ láti rí bibò òtítọ ìjọba Rè.
Isẹ́ ṣíṣe: Jésù kò wa láti gbàdúrà fún ìjọba tó mbò. Béèrè lówó àjèjì kan tí o bá lè gbàdúrà fún wọn nípa àwọn àìní wọn pàtó.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ní alẹ́ ìdákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ọdún 2000 sẹ́yìn, àwọn angẹli mu ìròyìn ìbí Olùgbàlà wá fún ẹgbẹ́ àwọn daran-daran kan níbi tí wọn ti ń da ẹran wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìròyìn náà, àwọn daran-daran wọ̀nyí fi ohun gbogbo sí'lẹ̀ láti wá ìkókó tí ó wà ní ibùjẹ ẹran ní Bẹtilẹhẹmu. Lẹ́yìn gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, ìpè yìí kò tíì yí padà. Ẹ̀ bá Dr. Charles Stanley rìn bí ó ṣe ń ràn yín l'ọ́wọ́ láti súnmọ́ Olùgbàlà, àti láti mú ọkàn yín le láti wá àyè láti sinmi nínú ìfẹ́ Bàbá ní àkókò yíì.
More