Ìrìn àjò lo si Ìbùje EranÀpẹrẹ

Journey To The Manger

Ọjọ́ 18 nínú 70

Rìn nípa Ìgbàgbó

Ìwé Mímó ràn wa létí pé òpò àwon okùnrin àti obìnrin olódodo wón kò rí ìkése járí ìrètí wón wá ìmúse àyàfi tí a bá dán ìgbàgbó wón wò gidigidi. Ní àwon ìsèlè kan, wón kò rí ìdáhùn tó jínlè sí lára àwon àdúrà wón lákókò ìgbésí ayé wón. Síbè èyí kò mú wón dáwó dúró nínú ìgbàgbó nínú Olórun lójoojúmó.

Kò sí ìkọ̀wé wòlíì ni Ìsráẹ́lì fún òrúndún mérin, síbè okùnrin àti obìnrin bí Síméónì àti Ánà —àwon oníwa bí Olórun ñ dúró àti retí Mèsáyà gangan —wón dì ìgbàgbó wón mú pé Olúwa yóò se ohun Tó ni Òun yóò se gangan. Wón kò í tí juwó ìretí sílè kódà ní ojó ogbó wón. Abájo tí wón dà ènì tí wón retí tipétipé mò lésékésé nígbà tí wón rí I ni apá ìya Rè—bó tí lè jé pé kò sí elómìrán tó dà mò.

Kò jé ǹkan kan pé ebí òdó yìí jé tàlàká, tó ñ mú ebo tó kéré jùlo olówó ńlá wá sí téńpìlì-. Síméónì àti Ánà dà ọmọ aládé mò lójú esè nítorí wón wà ni ìrẹ́pọ̀ nígbà gbogbo pèlú Olórun, wón rìn nípa ìgbàgbó dípò ojú..

Isé Sísé on: Sètore ohun ìseré tuntun sí ẹgbẹ́ aláàánú tó fọkàn tán tó ñ pín àwon èbùn Kérésìmesì fún àwon omodé tó saláìní.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 17Ọjọ́ 19

Nípa Ìpèsè yìí

Journey To The Manger

Ní alẹ́ ìdákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ọdún 2000 sẹ́yìn, àwọn angẹli mu ìròyìn ìbí Olùgbàlà wá fún ẹgbẹ́ àwọn daran-daran kan níbi tí wọn ti ń da ẹran wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìròyìn náà, àwọn daran-daran wọ̀nyí fi ohun gbogbo sí'lẹ̀ láti wá ìkókó tí ó wà ní ibùjẹ ẹran ní Bẹtilẹhẹmu. Lẹ́yìn gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, ìpè yìí kò tíì yí padà. Ẹ̀ bá Dr. Charles Stanley rìn bí ó ṣe ń ràn yín l'ọ́wọ́ láti súnmọ́ Olùgbàlà, àti láti mú ọkàn yín le láti wá àyè láti sinmi nínú ìfẹ́ Bàbá ní àkókò yíì. 

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò visit: https://intouch.cc/yv18