Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Ọjọ́ 13 nínú 13

Ayé Èlíṣà wá sí òpin ní Àwọn Ọba 13:10-21. Iṣẹ́ ìyanu ìkẹyìn rẹ̀ sì wáyé lẹ́yìn ikú àti ìsìnkú rẹ̀. Àwọn adigunjalè láti ìlú Móábù kọlù Ísráẹ́lì nígbà tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kan ń sin ọmọkùnrin kan. Ìkọlù yìí dé bá wọn l'òjijì, wọ́n sì ju òkú náà sì ibojì Èlíṣà. Ṣùgbọ́n nígbà tí ara òkú náà kan egungun Èlíṣà, ó jíǹde! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Elíshà ti wà nípò òkú, Ọlọ́run tẹ̀síwájú láti máa lo Èlíṣà gẹ́gẹ́ bíi ikọ̀ fún ǹkan meré-meré nínú ayé àwọn ẹlòmíràn. Èlíṣà jẹ́ wòlíì tí ìgbàgbọ́, ìgbọ́ràn, àánú àti ìgboyà rẹ̀ yani lẹ́nu. Bóyá ní ti jíjẹ́ kí orí àáké léfòó lójú omi ni, tàbí sísun ẹ̀rọ ìtulẹ̀ rẹ̀ láti jẹ́ Èlíjà n'ípè ni, tàbí jíjí òkú dìde lẹ́yìn tí oun tìkárarẹ̀ ti kú ni, láì ṣe àní-àní, Èlíṣà jẹ́ ọ̀kàn lára àwọn ènìyàn méle-gbàgbé nínú Bíbélì.

Àsìkò láti jẹ́ ènìyàn ìyàlẹ́nu gẹ́gẹ́ bíi Èlíṣà dé tán kí o sì yọ gbogbo ìjánu lẹ́sẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ! Àsìkò tó láti máa gbé ìgbésẹ̀ tó lè ya ayé l'énu. Èlíṣà jẹ́ àpẹẹrẹ pípé bí ìgbésí-ayé ènìyàn ti lè rí bí a bá pinnu láti jọ̀wọ́ oun gbogbo kí a ba lè gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ ìyanu. Nígbà tí o bá jọ̀wọ́ gbogbo rẹ̀ tí o sì fi wọ́n fún Olúwa, Ó lè ṣe àwọn ǹkan àràmàǹdà nínú ayéè rẹ, tí ìwọ fúnra rẹ ò mò pé ó ṣeéṣe. Ọwọ́ rẹ ló wá kù sí báyìí. Àwọn ìgbésẹ wo lo ní láti gbé kí ìgbàgbọ́ rẹ lè mú ìyanu dání bíi ti Èlíṣà?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 12

Nípa Ìpèsè yìí

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.

More

We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church