Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ
Nínú Ìwé Àwọn Ọba Kejì 4:38-44, Èlíṣà tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ èyí tó fara jọ àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù. Nínú iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, Èlíṣà pa oró májèlé tó wà nínú ọbẹ̀ aládùn tí a pèsè fún àwọn Àlùfáà. Nínú iṣẹ́ ìyanu kejì ni Èlíṣà ti sọ búrẹ́dì ogún tí a fi ọkà-bálì ṣe di ọ̀pọ̀ ìlọ́po tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi tó láti bọ́ ènìyàn ọgọ́rùn-ún. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí jẹ́ àpẹẹrẹ mìíràn nípa àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà lo Èlíṣà láti bá àìní àwọn ènìyàn pàdé. Ó ṣeé ṣe kí o ti jẹ "ọbẹ̀ aládùn onímájèlé" láìmọ̀ tí Ọlọ́run sì ti wò ọ́ sàn. Bóyá ǹkan tó ṣeé fojú rí ni tàbí ǹkan tí o kàn ní ìmọ̀lára rẹ̀ nípasẹ̀ èrò inú rẹ. Bóyá o tilẹ̀ ní ǹkan bíi májèlé nínú ayé rẹ nísinsìnyí tí o kò lè yọ kúrò tìkára rẹ̀ tó sì jẹ́ pé nípa agbára Ọlọ́run nìkan ni a fi lè yọ ọ́. Gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe ti ọbẹ̀ náà ní wẹ́rẹ́, Ọlọ́run lè yọ gbogbo májèlé ayéè rẹ kúrò kó sì sọ ọ́ dọ̀tun pẹ̀lú ìléra pípé. Májèlé wo mi Ọlọ́run ti mú kúrò láyé rẹ? Májèlé wo ni o nílò kí Ọlọ́run pa oró rẹ̀ nínú ayé rẹ ní àkókò yí?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church