Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Ọjọ́ 12 nínú 13

Àwọn Ọba Kejì 8:1-6 jẹ́ ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ kòńgẹ́ tó yani lẹ́nu. Nínú ìtàn yìí, a rí ìpadàbọ̀ obìrin Ṣúnẹ́mù, obìrin tí Elíshà jí ọmọ rẹ̀ padà láti ipò òkú, tí a rí kà nínú Àwọn Ọba 4. Obìrin náà pinu láti padà sí Ísráẹ́lì nítorí ìyàn tí ó mú ní ìlú tí ó sá lọ. Nígbà tí ó dé tó sì lọ ké sí ọba, ó ṣe kòńgẹ́ àsìkò tí Gehasi, èyí tí ńṣe ọmọlẹ́yìn Elíshà, ń sọ fún ọba bí a ti jí ọmọ rẹ̀ padà láti ipò òkú. Àkókò ìṣe kòńgẹ́ yìí jẹ́ kí ọba fùn obìrin náà ní ilẹ̀ rẹ̀ padà. Fún Ọlọ́run, kò sí oun tó ń jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kòńgẹ́.

Ronú nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú ayé rẹ tí o lérò wípé ó jẹ́ kòńgẹ́. Ó ṣeéṣe tí o bá w'ẹ̀yìn wò, kí àwọn ohun tí o fojú tẹ́ńbẹ́lú wò nígbà náà, ṣẹlẹ̀ nítorí Ọlọ́run wà lójú iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ètò Rẹ̀ fún ọ. Ó ṣe pàtàkì láti wà ní ìmúrasílẹ fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe wọnyii nítorí Ọlọ́run yíò tún ṣètò wọn lẹ́ẹ̀kan si. Jẹ́ akíkanjú nínú ìgbàgbọ́, kí ọ sì ríi dájú wípé ò ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wípé kí ó mú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìyanu Rẹ̀ ṣẹ̀ nínú ayéè rẹ léraléra, dípò ìrètí lásán fún ìṣẹ̀lẹ̀ kòńgẹ́. Rántí wípé kò sí ohun tíí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kòńgẹ́ tí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti lò. Ṣ'àpèjúwe akóko kan tí ọ ti ní ìrírí ìṣẹ̀lẹ̀ kòńgẹ́. Báwo ni o ṣe rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.

More

We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church