Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Ọjọ́ 10 nínú 13

Nínú ìwé Àwọn Ọba Kejì 6:8-23, ọba ẹ̀yà Aramu gbìyànjú láti mú Elíshà nítorí òun ló wà nìdìí ìṣẹ́gun Ísráẹ́lì lóri Aramu. Gbogbo ìgbà tí ọba bá gbìyànjú láti d'ojú kọ Ísráẹ́lì, Elíshà á kìlọ̀ fún ọba Ísráẹ́lì, ètò náà yóò sì bàjé. Nígbà tí ọmọlẹ́yìn Elíshà gbọ́ wípé ọba Aramu fẹ́ mú Elíshà, ẹ̀rù bàá títí Elíshà fi béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti ṣí ojú ọmọlẹ́yìn náà kí ó baà lè rí àwọn ògùn òrun tí ó wà ní ìhà tiwọn. Lẹ́yìn náà ni ó ní ìgboyà láti tẹ̀síwájú.

Àwọn ìgbà kan wà nínú ayé wa tí àwa náà máa ń dà bíi ọmọlẹ́yìn Elíshà; ojú wa ti fọ́ sí ohun tí ó yẹ kí a rí, nítorí náà, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn á bá wa. Ó lè jẹ́ pé ojú rẹ ti fọ́ sí àfẹ́sódì ohun kan tàbí ìbáṣepọ̀ tí ó ń kùnà. Ó lè jẹ́ pé ojú rẹ ti fọ́ sí òtítọ́, bóyá ìgbà tí ó bá tẹ́ẹ l'ọ́rùn tàbí tí o wà ní ilé ìjọsìn nìkan ni ò ń tẹ̀lé Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ pé ojú rẹ ti fọ́ sí òtítọ́ wípé o kò tíì dé ipele tí Ọlọ́run ń mú ọ lọ, dípò ìtẹ̀síwájú, ṣeni o wà nínú ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àìbìkítà. Ohun tí ì báà jẹ́ tí ojúù rẹ lè ti fọ́ sí, Ọlọ́run lè ṣí ojú rẹ láti rí òtítọ́. Ohun tí ó kù ni fún ọ láti jọ̀wọ́ ara rẹ fún-Un láti la ojú rẹ. Kíni ìwọ rò wípé ojú rẹ ti fọ́ sí tí ó yẹ kí o rí? Awọn ìgbésẹ̀ wo ni o má a gbé láti ṣí ojú rẹ?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 9Ọjọ́ 11

Nípa Ìpèsè yìí

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.

More

We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church