Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ
Ní Àwọn Ọba Kejì orí karùn-ún, a kà nípa Náámánì, olórí ogun ìlú àjòjì, ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, ṣùgbọ́n tó dẹ́tẹ̀. Ó gbọ́ l'ẹ́nu ẹrúbìrin rẹ̀ wípé Elíshà lè wò ó sàn. Nítorí náà, ó gbéra lọ sí Ísírẹ́lì pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn fún ọba. Nígbà tí Náámánì pàdé Èlíṣà, ó retí wípé Èlíṣà máa ju ọwọ́ tí ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ yóò sì pòórá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Èlíṣà sọ fún-un wípé kí ó ṣe ǹkan tí ó panilẹ́rín; ó sọ fún-un kí ó lọ ti ara rẹ̀ sí inú odò Jọ́dánì l'ẹ́ẹ̀méje, oun tí ó dàbí yẹ̀yẹ̀ sí Naamani. L'ákọ́kọ́, ó kọ̀ láti ṣe é, ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pàrowà fún-un, ó padà lọ. Nígbà tí ó gbọ́ràn, ó rí ìwosàn rẹ̀. Àmọ́ ìhà tí Náámánì kọ ṣáájú wọ́pọ̀ láàrin àwa ènìyàn.
Àwọn ìgbà míràn wà nínú ayé rẹ tí o ma fẹ́ ṣe àwọn ǹkan tí ó dà bíi pé Ọlọ́run ni ó ń darí rẹ láti ṣe, àmọ́ tí yóò dàbí àwàdà. Bóyá ìwọ náà ti béèrè oun kan l'ọ́wọ́ Ọlọ́run bíi ti Náámánì, àmọ́ ìdáhùn Rẹ̀ kìí ṣe oun tí o f'ọkàn sí, o kò sí ṣetán láti gba àwọn ètò Ọlọ́run pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Nígbà tí a bá bèrè oun kan l'ọ́wọ́ Ọlọ́run, kò yẹ fúnwa láti máa ṣe àlàálẹ̀ bí Ọlọ́run ti gbọ́dọ̀ dáhùn, tàbí ìgbà tí Ó gbọ́dọ̀ ṣeé ní pàtó. A kò ga ju Ọlọ́run lọ, a sì gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ kíkún sínú Rẹ̀ wípé yíò ṣe é nígbà tó tọ́, àti ní ọ̀nà tí ó yẹ. Àwa kọ́ ló ń darí ayé ara wa. Ọlọ́run ni adarí, gẹ́gẹ́ bíi Aísáyà 55:8 sì ti sọ fún wa, ọ̀nà Ọlọ́run kò dà bíi ti wa. Àwọn ìgbésẹ̀ wo lo ní láti gbé láti rẹ ara rẹ s'ílẹ̀ pátápátá níwájú Ọlọ́run, àti láti lè mọ̀ dájú wípé ọ̀nà Rẹ̀ kìí ṣe ọ̀nà tìrẹ?

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church