Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ
Tí a bá bẹ̀rẹ̀ láti Àwọn Ọba Kejì 6:24 títí dé orí 7, a máa rí àkọ́lé kan tí ó wọ́pọ̀ nínú ayé Èlíṣà èyí tí í ṣe àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà lo Elíshà láti pàdé àìní àwọn ènìyàn Rẹ̀. Nínú ìtàn yìí, ìyàn mú àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nítorí àwọn ẹ̀yà Aramia ṣé wọn mọ́ inú ìlú wọn. Elíshà sọ àsọtẹ́lẹ̀ wípé Ọlọ́run yíò pèsè oúnjẹ púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kì yóò ní iye. Àbájáde rẹ̀ sì yani lẹ́nu, torí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣàdédé ríi pé àwọn ọmọ ogun Aramu ti pòórá, wọ́n sì ti fi gbogbo oúnjẹ àti ohun èlò wọn sílẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan si, Ọlọ́run bá àìní àwọn ọmọ Ísráẹ́lì pàdé. Ọlọ́run wà fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, Ó sì wà fún ọ pẹ̀lú.
Ronú àwọn ìgbà tí o wà nínú àìní. Ronú àwọn ìgbà tí Ó ti gba ọ̀nà ara yọ, tí Ó sì bá àwọn àìní rẹ pàdé gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ìgbàanì. Fílípì 4:19 so fún wa wípé Ọlọ́run yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ Rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu. Ìlérí yìí sì jẹ́ òtítọ́ fún ọ lónìí bíi ti ìgbà wọnnì fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì. Ọlọ́run kò ní fi ọ́ sílẹ̀, yóò bá àwọn àìní rẹ pàdé, bí ó ti wù kí ó kéré tàbí tóbi. Àwọn ọ̀nà wo ni o ti rí bí Ọlọ́run ti bá àwọn àìní rẹ pàdé nínú ayé rẹ?

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church