O si ṣe lẹhìn eyi, ni Benhadadi ọba Siria ko gbogbo ogun rẹ̀ jọ, nwọn si gòke, nwọn si dó tì Samaria.
Iyàn nla kan si mu ni Samaria: si kiyesi i, nwọn dó tì i, tobẹ̃ ti a si fi ntà ori kẹtẹkẹtẹ kan ni ọgọrun iwọ̀n fadakà, ati idamẹrin oṣuwọn kabu imi ẹiyẹle, ni iwọ̀n fàdakà marun.
O si ṣe ti ọba Israeli nkọja lọ lori odi, obinrin kan sọkún tọ̀ ọ wá wipe, Gbà mi, oluwa mi, ọba!
On si wipe, Bi Oluwa kò ba gbà ọ, nibo li emi o gbe ti gbà ọ? Lati inu ilẹ-ipakà, tabi lati inu ibi ifunti?
Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ọ? On si dahùn wipe, Obinrin yi wi fun mi pe, Mu ọmọkunrin rẹ wá, ki awa ki o le jẹ ẹ loni, awa o si jẹ ọmọ ti emi li ọla.
Bẹ̃ni awa sè ọmọ mi, awa si jẹ ẹ́: emi si wi fun u ni ijọ keji pe, Mu ọmọ rẹ wá ki awa ki o jẹ́ ẹ; on si ti fi ọmọ rẹ̀ pamọ́.
O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ obinrin na, o fà aṣọ rẹ̀ ya; o si kọja lọ lori odi, awọn enia si wò, si kiyesi i, o ni aṣọ-ọfọ̀ labẹ aṣọ rẹ̀ li ara rẹ̀.
Nigbana ni o wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe bayi ati jù bẹ̃ lọ si mi, bi ori Eliṣa ọmọ Ṣafati yio duro li ọrùn rẹ̀ li oni.
Ṣugbọn Eliṣa joko ninu ile rẹ̀, ati awọn àgbagba joko pẹlu rẹ̀; ọba si rán ọkunrin kan ṣãju rẹ̀ lọ: ṣugbọn ki iranṣẹ na ki o to dé ọdọ rẹ̀, on wi fun awọn àgbagba pe, Ẹ wò bi ọmọ apania yi ti ranṣẹ lati mu ori mi kuro? ẹ wò, nigbati iranṣẹ na ba de, ẹ tì ilẹ̀kun, ki ẹ si dì i mu ṣinṣin li ẹnu-ọ̀na: iro-ẹsẹ̀ oluwa rẹ̀ kò ha wà lẹhin rẹ̀?
Bi on ti mba wọn sọ̀rọ lọwọ, kiyesi i, iranṣẹ na sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá: on si wipe, Wò o, lati ọwọ Oluwa ni ibi yi ti wá, kili emi o ha duro dè Oluwa mọ si?