II. A. Ọba 6:24-33

II. A. Ọba 6:24-33 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe lẹhìn eyi, ni Benhadadi ọba Siria ko gbogbo ogun rẹ̀ jọ, nwọn si gòke, nwọn si dó tì Samaria. Iyàn nla kan si mu ni Samaria: si kiyesi i, nwọn dó tì i, tobẹ̃ ti a si fi ntà ori kẹtẹkẹtẹ kan ni ọgọrun iwọ̀n fadakà, ati idamẹrin oṣuwọn kabu imi ẹiyẹle, ni iwọ̀n fàdakà marun. O si ṣe ti ọba Israeli nkọja lọ lori odi, obinrin kan sọkún tọ̀ ọ wá wipe, Gbà mi, oluwa mi, ọba! On si wipe, Bi Oluwa kò ba gbà ọ, nibo li emi o gbe ti gbà ọ? Lati inu ilẹ-ipakà, tabi lati inu ibi ifunti? Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ọ? On si dahùn wipe, Obinrin yi wi fun mi pe, Mu ọmọkunrin rẹ wá, ki awa ki o le jẹ ẹ loni, awa o si jẹ ọmọ ti emi li ọla. Bẹ̃ni awa sè ọmọ mi, awa si jẹ ẹ́: emi si wi fun u ni ijọ keji pe, Mu ọmọ rẹ wá ki awa ki o jẹ́ ẹ; on si ti fi ọmọ rẹ̀ pamọ́. O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ obinrin na, o fà aṣọ rẹ̀ ya; o si kọja lọ lori odi, awọn enia si wò, si kiyesi i, o ni aṣọ-ọfọ̀ labẹ aṣọ rẹ̀ li ara rẹ̀. Nigbana ni o wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe bayi ati jù bẹ̃ lọ si mi, bi ori Eliṣa ọmọ Ṣafati yio duro li ọrùn rẹ̀ li oni. Ṣugbọn Eliṣa joko ninu ile rẹ̀, ati awọn àgbagba joko pẹlu rẹ̀; ọba si rán ọkunrin kan ṣãju rẹ̀ lọ: ṣugbọn ki iranṣẹ na ki o to dé ọdọ rẹ̀, on wi fun awọn àgbagba pe, Ẹ wò bi ọmọ apania yi ti ranṣẹ lati mu ori mi kuro? ẹ wò, nigbati iranṣẹ na ba de, ẹ tì ilẹ̀kun, ki ẹ si dì i mu ṣinṣin li ẹnu-ọ̀na: iro-ẹsẹ̀ oluwa rẹ̀ kò ha wà lẹhin rẹ̀? Bi on ti mba wọn sọ̀rọ lọwọ, kiyesi i, iranṣẹ na sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá: on si wipe, Wò o, lati ọwọ Oluwa ni ibi yi ti wá, kili emi o ha duro dè Oluwa mọ si?

II. A. Ọba 6:24-33 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, Benhadadi, ọba Siria, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti bá Israẹli jagun, wọ́n sì dóti ìlú Samaria. Nítorí náà, ìyàn ńlá mú ní ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ọgọrin ìwọ̀n ṣekeli fadaka ati idamẹrin òṣùnwọ̀n kabu ìgbẹ́ ẹyẹlé ní ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un. Bí ọba Israẹli ti ń rìn lórí odi ìlú, obinrin kan kígbe pè é, ó ní, “Olúwa mi, ọba, ràn mí lọ́wọ́.” Ọba dáhùn pé, “Bí OLUWA kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ wo ni èmi lè ṣe? Ṣé mo ní ìyẹ̀fun tabi ọtí waini ni?” Ó bá bèèrè pé, “Kí ni ìṣòro rẹ?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin yìí sọ fún mi pé kí n mú ọmọ mi wá kí á pa á jẹ, bí ó bá di ọjọ́ keji a óo pa ọmọ tirẹ̀ jẹ, ni a bá pa ọmọ tèmi jẹ. Ní ọjọ́ keji, mo sọ fún un pé kí ó mú ọmọ tirẹ̀ wá kí á pa á jẹ, ṣugbọn ó fi ọmọ tirẹ̀ pamọ́.” Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Àwọn tí wọ́n wà lẹ́bàá odi níbi tí ó ń gbà lọ sì rí i pé ó wọ aṣọ-ọ̀fọ̀ sí abẹ́ aṣọ rẹ̀. Ó sì búra pé kí OLUWA ṣe jù bẹ́ẹ̀ sí òun bí òun kò bá gé orí Eliṣa, ọmọ Ṣafati, kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú. Eliṣa jókòó ninu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn alàgbà. Ọba rán ọkunrin kan ṣáájú láti lọ pa á, ṣugbọn Eliṣa sọ fún àwọn alàgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ apànìyàn yìí ti rán ẹnìkan láti wá pa mí, ọba fúnra rẹ̀ sì ń tẹ̀lé e bọ̀ lẹ́yìn. Bí iranṣẹ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà kí ó má lè wọlé.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dé, ó ní, “Láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni ibi yìí ti wá, kí ló dé tí n óo fi tún máa dúró de OLUWA fún ìrànlọ́wọ́?”

II. A. Ọba 6:24-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ni Beni-Hadadi ọba Aramu kó gbogbo àwọn ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì yan sókè wọ́n sì dúró ti Samaria. Ìyàn ńlá sì mú ní ìlú Samaria; wọ́n dúró tí ì tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n fàdákà àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n kábù imí ẹyẹlé, fún ìwọ̀n fàdákà márùn-ún. Gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sọkún sí i pé, “Ràn mí lọ́wọ́, olúwa ọba mi!” Ọba sì dá a lóhùn pé, “Bí OLúWA kò bá gbà ọ́, níbo ni èmi yóò gbé ti gbà ọ́? Láti inú ilẹ̀ ìpakà, tàbí láti inú ibi ìfúntí?” Nígbà náà ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’ Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.” Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀. Ó sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Eliṣa ọmọ Ṣafati kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní!” Nísinsin yìí Eliṣa jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbàgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Eliṣa sọ fún àwọn àgbàgbà pé, “Ṣé ẹ̀yin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dìímú ṣinṣin ní ẹnu-ọ̀nà, ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ kò ha wà lẹ́yìn rẹ?” Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a. Ọba náà sì wí pé, “Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ OLúWA ni. Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de OLúWA sí i?”