ÀWỌN ỌBA KEJI 6

6
Irin Àáké Léfòó
1Ní ọjọ́ kan àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Eliṣa sọ fún un pé, “Ibi tí à ń gbé kéré jù fún wa. 2Jọ̀wọ́ fún wa ní ààyè láti lọ gé igi ní etí odò Jọdani láti fi kọ́ ilé mìíràn tí a óo máa gbé.”
Eliṣa dáhùn pé, “Ó dára, ẹ máa lọ.”
3Ọ̀kan ninu wọn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá àwọn lọ, ó sì gbà bẹ́ẹ̀. 4Gbogbo wọn jọ lọ, nígbà tí wọ́n dé etí odò Jọdani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé igi. 5Bí ọ̀kan ninu wọn ti ń gé igi, lójijì, irin àáké tí ó ń lò yọ bọ́ sinu odò. Ó kígbe pé, “Yéè! Oluwa mi, a yá àáké yìí ni!”
6Eliṣa bèèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?”
Ọkunrin náà sì fi ibẹ̀ hàn án. Eliṣa gé igi kan, ó jù ú sinu omi, irin àáké náà sì léfòó lójú omi. 7Eliṣa pàṣẹ fún un pé, “Mú un.” Ọkunrin náà bá mu irin àáké náà.
Israẹli Ṣẹgun Siria
8Ní ìgbà kan tí ọba Siria ń bá ọba Israẹli jagun, ó bá àwọn olórí ogun rẹ̀ gbèrò ibi tí wọn yóo ba sí de àwọn ọmọ ogun Israẹli. 9Eliṣa ranṣẹ sí ọba Israẹli pé kí ó má ṣe gba ibẹ̀ nítorí pé àwọn ará Siria ba sibẹ. 10Ọba Israẹli bá ranṣẹ sí àwọn eniyan tí ń gbé ibi tí Eliṣa kilọ̀ fún un nípa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ níí máa ń kìlọ̀ fún ọba Israẹli tí ọba Israẹli sì ń bọ́ kúrò ninu tàkúté ọba Siria. Ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà.
11Ọkàn ọba Siria kò balẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ yìí, nítorí náà, ó pe gbogbo àwọn olórí ogun rẹ̀ jọ, ó sì bi wọ́n pé, “Ta ló ń tú àṣírí wa fún ọba Israẹli ninu yín?”
12Ọ̀kan ninu wọn dáhùn pé, “Kò sí ẹnìkan ninu wa tí ń sọ àṣírí fún ọba Israẹli. Wolii Eliṣa ní ń sọ fún un, títí kan gbogbo ohun tí ẹ bá sọ ní kọ̀rọ̀ yàrá yín.”
13Ọba bá pàṣẹ pé, “Ẹ lọ wádìí ibi tí ó ń gbé, kí n lè ranṣẹ lọ mú un.”
Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé Eliṣa wà ní Dotani, 14ó rán ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun ati ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun lọ sibẹ. Ní òru ni wọ́n dé ìlú náà, wọ́n sì yí i po. 15Ní òwúrọ̀ kutukutu, nígbà tí iranṣẹ Eliṣa jáde sí ìta, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Siria ti yí ìlú náà po pẹlu ẹṣin ati àwọn kẹ̀kẹ́-ogun. Ó pada wọlé tọ Eliṣa lọ, ó sì kígbe pé, “Yéè, oluwa mi, kí ni a óo ṣe?”
16Eliṣa dáhùn pé, “Má bẹ̀rù nítorí pé àwọn tí wọ́n wà pẹlu wa ju àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn lọ.” 17Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká.
18Nígbà tí àwọn ará Siria gbìyànjú láti mú un, ó gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ fọ́ àwọn ọkunrin náà lójú. OLUWA sì fọ́ wọn lójú gẹ́gẹ́ bí adura Eliṣa. 19Eliṣa tọ̀ wọ́n lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣìnà; èyí kì í ṣe ìlú tí ẹ̀ ń wá, ẹ tẹ̀lé mi n óo fi ẹni tí ẹ̀ ń wá hàn yín.” Ó sì mú wọn lọ sí Samaria.
20Ní kété tí wọ́n wọ Samaria, Eliṣa gbadura pé kí OLUWA ṣí wọn lójú kí wọ́n lè ríran. OLUWA sì ṣí wọn lójú, wọ́n rí i pé ààrin Samaria ni àwọn wà.
21Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó bi Eliṣa pé, “Ṣé kí n pa wọ́n, oluwa mi, ṣé kí n pa wọ́n?”
22Eliṣa dáhùn pé, “O kò gbọdọ̀ pa wọ́n, ṣé o máa pa àwọn tí o bá kó lójú ogun ni? Gbé oúnjẹ ati omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n mu, kí wọ́n sì pada sọ́dọ̀ oluwa wọn.” 23Nítorí náà, ọba Israẹli pèsè oúnjẹ fún wọn lọpọlọpọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n sì ti mu, wọ́n pada sọ́dọ̀ oluwa wọn. Láti ọjọ́ náà ni àwọn ọmọ ogun Siria kò ti gbógun ti ilẹ̀ Israẹli mọ́.
Ogun Dóti Samaria
24Lẹ́yìn èyí, Benhadadi, ọba Siria, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti bá Israẹli jagun, wọ́n sì dóti ìlú Samaria. 25Nítorí náà, ìyàn ńlá mú ní ìlú náà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ọgọrin ìwọ̀n ṣekeli fadaka ati idamẹrin òṣùnwọ̀n kabu ìgbẹ́ ẹyẹlé ní ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un.
26Bí ọba Israẹli ti ń rìn lórí odi ìlú, obinrin kan kígbe pè é, ó ní, “Olúwa mi, ọba, ràn mí lọ́wọ́.”
27Ọba dáhùn pé, “Bí OLUWA kò bá ràn ọ́ lọ́wọ́, ìrànlọ́wọ́ wo ni èmi lè ṣe? Ṣé mo ní ìyẹ̀fun tabi ọtí waini ni?” 28Ó bá bèèrè pé, “Kí ni ìṣòro rẹ?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin yìí sọ fún mi pé kí n mú ọmọ mi wá kí á pa á jẹ, bí ó bá di ọjọ́ keji a óo pa ọmọ tirẹ̀ jẹ, 29ni a bá pa ọmọ tèmi jẹ. Ní ọjọ́ keji, mo sọ fún un pé kí ó mú ọmọ tirẹ̀ wá kí á pa á jẹ, ṣugbọn ó fi ọmọ tirẹ̀ pamọ́.”#Diut 28:57; Eks Jer 4:10
30Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Àwọn tí wọ́n wà lẹ́bàá odi níbi tí ó ń gbà lọ sì rí i pé ó wọ aṣọ-ọ̀fọ̀ sí abẹ́ aṣọ rẹ̀. 31Ó sì búra pé kí OLUWA ṣe jù bẹ́ẹ̀ sí òun bí òun kò bá gé orí Eliṣa, ọmọ Ṣafati, kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú. 32Eliṣa jókòó ninu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn alàgbà. Ọba rán ọkunrin kan ṣáájú láti lọ pa á, ṣugbọn Eliṣa sọ fún àwọn alàgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ apànìyàn yìí ti rán ẹnìkan láti wá pa mí, ọba fúnra rẹ̀ sì ń tẹ̀lé e bọ̀ lẹ́yìn. Bí iranṣẹ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà kí ó má lè wọlé.” 33Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọba dé, ó ní, “Láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni ibi yìí ti wá, kí ló dé tí n óo fi tún máa dúró de OLUWA fún ìrànlọ́wọ́?”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KEJI 6: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa