Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ
Bíi wípé gbogbo ìgbésí-ayé Èlíṣà ló jẹ́ kìkìdá kàyéfì tí ó sì kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó yani lẹ́nu. Ọ̀kan lára èyí tó ṣeni ní kàyéfì l'arí nínú Àwọn Ọba Kejì 6:1-7. Nínú àyọkà yìí, a rí ìkórajọpọ̀ àwọn wòlíì tí ń gé igi lulẹ̀ pẹ̀lú àáké, pẹ̀lú ìpinnu láti fi igi náà kọ́ àwọn ilé tuntun. Orí àáké ọ̀kan lára àwọn wòlíì náà bọ́ s'ómi, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ṣeni wọ́n yá a. Èlíṣà dáhùn nípa mímú igi kan ó sì jù ú síbi tí orí àáké náà jìn sìí. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni orí àáké náà si léfòó padà sójú omi. Tí o bá kọ́kọ́ kà ìtàn yìí, o lè jọ pé kò sí ẹ̀kọ́ kan pàtó nínú rẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ ǹkan ló wà fúnwa láti ríkọ́ nínú ìtàn yìí. Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn ǹkan tí o ti pàdánù. Kò sí aájò rẹ tó kéré níwájú Ọlọ́run wa, bó ṣe orí àáké tó sọnù.
Kí lo ti pàdánù? Bóyá o ti pàdánù ìbùkún, ìbáṣepọ̀, àlàáfíà, ipá láti ṣe ìṣúná, orúkọ rere, tàbí ohun mìíràn? Ìròyìn ayò ibẹ̀ ni wípé Ọlọ́run bìkítà gidi gan-an nípa ohunkóhun tí ó lè ti sọnù Ó sì ṣe tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́ fún ìmúbọ̀sípò àwọn ǹkan tí o pàdánù. Ọlọ́run lè bá ọ wá ohun ti o sọnù nípa bíbẹ̀rẹ̀ láti máa wò ibi tó ti jábó. Padà sí ibi tí o ti kúrò lójú ọ̀nà kí o sì gbà Ọlọ́run láàyè láti dá ọ padà sí ipa tótọ́. O lè ní láti dẹkùn nǹkan kan kí o sì bẹ̀rẹ̀ ohun tó yàtọ̀. Orí àáké rẹ kò tíì ṣègbé; ó kàn wà níbi tí o fiílẹ̀ sí ni. Ọlọ́run lè rú òfin òǹfà-ilẹ̀ láti dáa padà fún ọ. Kí ni ohun tí ó sọnù tí o nílò kí Ọlọ́run gbà padà fún ọ? Ọ̀nà wo ló máa gbà ṣeé?

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church