Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Ọjọ́ 1 nínú 13

Ìtàn Èlíṣà bẹ̀rẹ̀ láti Ìwé Ọba Kìíní 19:14-21 bí Ọlọ́run se sò fún Èlíjà láti fòróró yan Èlíṣà gẹ́gẹ́ bí wòlíì tó má rọ́pòo rẹ̀. Nínú àyọkà yìí a ri kà wípé Èlíjà rí Èlíṣà tó ń túlè lórí pápá pèlú màlúù méjì tí ó sì fi aṣọ ìwọ̀léke rẹ̀ lé Èlíṣà lára lójú-ẹsẹ̀ èyí tó fi ẹsẹ̀ ìpèe Èlíṣà múlẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kẹsẹ̀ ni Èlíṣà sègbọràn tí ó sì jó èèlò ìtulẹ̀ rẹ̀ tí ó sì fi igi àjàgà yìí se àwon màálù náà fún àwọn ọ̀rẹ́ rè láti jẹ. Èlíṣà se àfihàn ìfara-enijìn tí ó pe ni níjà sí Èlíjà. Kò pàdánù àkókò láti se ìgbọràn. Kò tọrọ gáfárà láti lọ ronú nípa ìpè náà. Kò ṣòpò ṣe àgbéyèwò àǹfààní tàbí ewu tí yóò kojú. Kò kọbiara sí ìṣọ́ra. Lẹ́sẹ̀ kẹsẹ̀ ló dáhùn sí ìpè láti tẹ̀lé Ọlọ́run nípasẹ̀ Èlíjà.

Ìfara-enijìn tí ó pe ni níjà tí Èlíṣà fi hàn wípé títẹ̀lé Ọlọ́run jẹ́ iṣẹ́ ńlá, àmọ́ àìtẹ̀lé E máa ń mú ìjìyà ńlá dání. Síwájú sí, ìfarajìn Èlíṣà kò yọ ǹkankan sílẹ̀. O jo àwọn èèlò ìtúlẹ̀ rẹ̀, ó pa àwọn màlúù rẹ̀, ó sì tún pa àwọn ẹ̀tọ́ àti ogún rẹ̀ tì. Ó fi gbogbo ohun tó mọ̀ tí ó sì fẹ́ràn sílè. Èlíṣà fi hàn wa pé láti sún mọ́ sàkání kádàrá, o ní láti gbé ìgbésẹ̀ kúrò ní kọ̀rọ̀ ìdẹ̀ra. Ǹjẹ́ ìfara-enijìn ojú-ẹsẹ̀ sí Ọlọ́run tí kò yọ ńkankan sílẹ̀ bíi tí Èlíṣà ni ìwọ ní? Àwọn ǹkan ìdẹ̀ra wo ni o nílò láti mú kúrò kí o tó lè bá ìlépa kádàrá rẹ?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.

More

We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church