Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Ọjọ́ 4 nínú 13

Orí kẹ́ta nínú Ìwé Àwọn Ọba Kejì jẹ́ ìtàn àkà-túnkà níbi tí àwọn ọba ìlú Ísírẹ́lì, Júdà, àti Édómù tí fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti jà ogún kan tí wọ́n lérò wípé yóò rọrùn láti borí, àmọ́ ǹkan ò lọ bí wọ́n ti ṣètò rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn ọba náà tọ Èlíṣà lọ fún ìrànlọ́wọ́ nípa ìjà náà. Ìdáhùn Èlíṣà sí àwọn ọba náà kì í se ohun tí wọ́n ń retí. Èlíṣà wí fún wọn wípé (ni King James Version) kí wọ́n lọ gbẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòtò àti wípé Ọlọ́run yóò kún àwọn kòtò náà pẹ̀lú omi, tí yóò sì ró àwọn ọmọ-ogun àti màlúù wọn lágbára. Tí wọn ba se èyí, Èlíṣà sọ fún àwọn Ọba náà pé Ọlọ́run yóò jọ̀wọ́ Móábù lé won lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí àbá Èlíṣà yí ya àwọn ọba náà lẹ́nu, àmọ́ wọ́n gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́ wọ́n sì ṣe ohun tí a dárí wọn láti ṣe.

Ìtàn yìí dá lórí ìgbàgbọ́. Ọlọ́run nìkan lo lè fi omi fúnwa, àmọ́ Ó fẹ́ kí a gbẹ́ kòtò láti fi gbà á. Tí o bá fẹ́ rí omi nínú ayé rẹ̀, dìde kí o sì gbẹ́ kòtò. Ìgbàgbọ́ òtítọ́ ń ṣiṣẹ́ àti pé ó máa ń gbà ohun ńlá gbọ́, àmọ́ o ni láti ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ níbi kékeré. Ìwọ̀n ìran rẹ̀ kò tóbi jù fún Ọlọ́run láti mú wá sí ìmúṣẹ. Ọ̀pọ̀ ni kòní ìran tí ó tóbi tó, bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀ ò ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ níbi kékeré. Báwo ni a ti ń gbẹ́ kòtò? Mú “ṣọ́bìrì” rẹ̀ kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ́ ilẹ̀ náà díẹ̀ díẹ̀. O kò lè retí kí Ọlọ́run fún ọ ni àwọn ohun mèremère tí o kò bá ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ níbi kékeré. Ní ìgbàgbó ńlá. Bẹ̀rẹ̀ níbi kékeré. Fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ sẹ́nu iṣẹ́ nípa gbígbẹ́ kòtò mélòó kan. Kí ni ìran ńlá tí o ní ti o nílò ìránlọ́wọ́ Ọlọ́run láti ṣe àṣeparí rẹ̀? Kíni àwọn kòtò kéékèèké tí o nílò láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ́ fún ìran náà láti wá sí ìmúṣẹ?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Elisha: A Tale Of Ridiculous Faith

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.

More

We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church