Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Nínú Àwọn Ọba Kejì 2:19-22, A rí àkọ́kọ́ lára ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Èlíṣà ṣe. Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ dá lóríi sísọ omi aláìléso ti Jẹ́ríkò di mímọ́. Ọlọ́run lo Èlíṣà gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìfẹ́ Rẹ̀ láti bá àìní àwọn mìíràn pàdé. Bí Èlíṣà, Ọlọ́run sábà máa ń lo wa bí ohun èlò ìfẹ́ Rẹ̀ láti ràn àwọn tó ń se àìní lọ́wọ́. Jókòó lónìí kí o sì ronú nípa ẹnì tí o mọ̀ pé o nílò ìrànlówọ́ àti àwọn ìgbése tí o lè gbé láti se ìrànwọ́ fún wọ́n nípa bíbá àìní wọn pàdé. Taló ní àìní kan tí ìwọ lè ba pàdé? Ki ni ìgbése tí o ma gbé láti ba àìní náà pàdé?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church