Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ
Nínú Àwọn Ọba Kejì 2:1-18 a ríi pé ìfarajìn Èlíṣà tó peni níjà tí Èlíṣà ní sí Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. Kí a tó gbà Èlíjà sókè sí ọ̀run, Ọlọ́run pè é láti bẹ̀ Bẹ́tẹ́lì wò, ó sì sọ fún Èlíṣà kó dúró sílé. Ìfarajìn Èlíṣà sí Ọlọ́run pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò gba ẹ̀bẹ̀ Èlíjà tí ó sì tẹ̀le lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Èyí kìí se ìṣẹ̀lẹ̀ èèkàn ṣoṣo bí a ti ríi pé Èlíṣà sin Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀dodo títí di ọjọ́ tí ó fi kú. Òhun ni àpẹẹrẹ àlàyé nípa ènìyàn tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà fún Ọlọ́run. Orí ìwọ̀n wo ni ìfarajìn rẹ sí Ọlọ́run wà? Ṣé gbogbo ọ̀nà lo ti f'ara rẹ jìn àbí o kan fara jìn nígbà tí ó rọrùn nìkan?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church