Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Bóyá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe àti ìpèníjà tí o máa ń kojú nínú àwọn ìgbésẹ̀ rẹ lo máa ń fa ìpòrúru ọkàn? Àbí o lérò wípé kò sí ọ̀nà àbáyọ mọ́ àti wípé àpò sùúrù rẹ pẹ̀lú ti fẹ́rẹ̀ ṣófo? Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ohun tó wá sọ́kàn ìyàwó àlùfáà tó di olóògbé nínú ìwé Àwọn Ọba Kejì 4:1-7. Lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀, ó ní ìdojúkọ ìṣúná ó sì wà nínú ìbẹ̀rù pípàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀--títí kan àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀--tí àwọn ayánilówó ṣe tán láti kó lọ. O béèrè lọ́wọ́ Èlíṣà fún ìrànlówọ́. Nígbà tí Èlíṣà sì bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun tó ní láti ṣisé pẹ̀lú, ó da lóhùn pé òun kò ni ohunkóhun rárá bíkòṣe kólòbó òróró kékeré kan. Bóyá ìwọ náà ti bá ára rẹ ní irú ipò yí rí nígbà tí o lérò wípé o kò ní ànító, ara rẹ kò balẹ̀ pẹ̀lú ìrònú nípa àìní tó gba àyà rẹ kan. Ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ń rí ìṣòro rẹ yàtọ̀ kedegbe sí ọ̀nà tí ìwọ ń gba wòó.
Láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin Ìwé Mímọ́ ni a ti rí onírúurú àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe ń lo ìṣúra kékeré láti bá àìní tó kani láyà pàdé, ìtàn yí sì jẹ́ àpẹẹrẹ irú rẹ̀ tó tayọ. Ayé lè rí èyí bí ohun tí kò mọ́gbọ́n dání tàbí ohun tí à ń bẹnu àtẹ́ lù, àmọ́ Ọlọ́run kò ri bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run mú kólòbó òróró kan ó sì sọ ọ́ di ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlọ́po tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí opó náà san gbogbo gbèsè rẹ̀. Nígbàkúùgbà tí ọkàn rẹ bá pòrúru tí kò sí ọ̀nà àbáyọ mọ́, rántí pé ìṣúra kékeré rẹ ti tó fún Ọlọ́run láti ṣiṣẹ́. Ọlọ́run ti fi ohun gbogbo tí o nílò sí ìkáwọ́ rẹ. Apá wo nínú ìgbésí-ayé rẹ lo ti ní ìpòrúru tí o sì lérò wípé ìṣúra rẹ ti tán? Kí ni àwọn ohun tí o ní tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àyípadà àfojúsùn rẹ?

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church