OBIRIN kan ninu awọn obinrin ọmọ awọn woli ke ba Eliṣa wipe, Iranṣẹ rẹ, ọkọ mi kú; iwọ si mọ̀ pe iranṣẹ rẹ bẹ̀ru Oluwa: awọn onigbèse si wá lati mu awọn ọmọ mi mejeji li ẹrú. Eliṣa si wi fun u pe, Kini emi o ṣe fun ọ? Wi fun mi, kini iwọ ni ninu ile? On si wipe, Iranṣẹbinrin rẹ kò ni nkankan ni ile, bikòṣe ikòko ororo kan. On si wipe, Lọ, ki iwọ ki o yá ikòko lọwọ awọn aladugbò rẹ kakiri, ani ikòko ofo; yá wọn, kì iṣe diẹ. Nigbati iwọ ba si wọle, ki iwọ ki o se ilẹ̀kun mọ ara rẹ, ati mọ awọn ọmọ rẹ, ki o si dà a sinu gbogbo ikòko wọnni, ki iwọ ki o si fi eyiti o kún si apakan. O si lọ kuro lọdọ rẹ̀, o si se ilẹ̀kun mọ ara rẹ̀ ati mọ awọn ọmọ rẹ̀, ti ngbe ikòko fun u wá; on si dà a. O si ṣe, nigbati awọn ikòko kún, o wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Tun mu ikòko kan fun mi wá. On si wi fun u pe, Kò si ikòko kan mọ. Ororo na si da. Nigbana li o wá, o si sọ fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Lọ, tà ororo na, ki o si san gbèse rẹ, ki iwọ ati awọn ọmọ rẹ ki o si jẹ eyi ti o kù.
Kà II. A. Ọba 4
Feti si II. A. Ọba 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 4:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò