II. A. Ọba 4:1-7

II. A. Ọba 4:1-7 Yoruba Bible (YCE)

Iyawo ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tọ Eliṣa lọ, ó sì sọ fún un pé, “Olúwa mi, iranṣẹ rẹ, ọkọ mi, ti kú, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ó jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA nígbà ayé rẹ̀. Ẹnìkan tí ó jẹ lówó kí ó tó kú fẹ́ kó àwọn ọmọkunrin mi mejeeji lẹ́rú, nítorí gbèsè baba wọn.” Eliṣa bèèrè pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ? Sọ ohun tí o ní nílé fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “N kò ní ohunkohun, àfi ìkòkò òróró kan.” Eliṣa sọ fún un pé, “Lọ yá ọpọlọpọ ìkòkò lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ. Lẹ́yìn náà, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ wọlé, nígbà tí ẹ bá sì ti ti ìlẹ̀kùn yín tán, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà, kí ẹ sì máa gbé wọn sí ẹ̀gbẹ́ kan bí wọ́n bá ti ń kún.” Obinrin náà lọ sinu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn wọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń gbé wọn wá. Nígbà tí gbogbo àwọn ìkòkò náà kún, obinrin náà bèèrè bóyá ìkòkò kù, àwọn ọmọ rẹ̀ sì dáhùn pé ó ti tán, òróró náà sì dá. Ó bá pada lọ sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wolii Eliṣa. Eliṣa wí fún un pé, “Lọ ta àwọn òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ ninu rẹ̀, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ máa ná ìyókù.”

II. A. Ọba 4:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sọkún tọ Eliṣa wá, “Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún OLúWA. Ṣùgbọ́n Nísinsin yìí onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀.” Eliṣa dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?” “Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá,” Ó wí pé, “àyàfi òróró kékeré.” Eliṣa wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìkòkò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré. Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ́kun dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìkòkò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kó o sí apá kan.” Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ìlẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìkòkò wá fún un ó sì ń dà á. Nígbà tí gbogbo ìkòkò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.” Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìkòkò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́. Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.”