Awọn ọkunrin ilu na si wi fun Eliṣa pe, Kiyesi i, itẹ̀do ilu yi dara, bi oluwa mi ti ri i: ṣugbọn omi buru, ilẹ si ṣá. On si wipe, Mu àwokóto titun kan fun mi wá, si fi iyọ̀ sinu rẹ̀; nwọn si mu u tọ̀ ọ wá. On si jade lọ si ibi orisun omi na, o si dà iyọ na sibẹ, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ṣe àwotan omi wọnyi; lati ihin lọ, kì yio si ikú mọ, tabi aṣálẹ. Bẹ̃ni a ṣe àwotan omi na titi di oni oloni, gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa ti o sọ. O si gòke lati ibẹ lọ si Beteli: bi o si ti ngòke lọ li ọ̀na, awọn ọmọ kekeke jade lati ilu wá, nwọn si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si wi fun u pe, Gòke lọ, apari! gòke lọ, apari! O si yipada, o si wò wọn, o si fi wọn bú li orukọ Oluwa. Abo-beari meji si jade lati inu igbó wá, nwọn si fà mejilelogoji ya ninu wọn. O si ti ibẹ lọ si òke Karmeli; ati lati ibẹ o pada si Samaria.
Kà II. A. Ọba 2
Feti si II. A. Ọba 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 2:19-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò