II. A. Ọba 2
2
A gbé Elija lọ sọ́run
1O si ṣe, nigbati Oluwa nfẹ lati fi ãjà gbé Elijah lọ si òke ọrun, ni Elijah ati Eliṣa lọ kuro ni Gilgali.
2Elijah si wi fun Eliṣa pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Beteli. Eliṣa si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn sọ̀kalẹ lọ si Beteli.
3Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Beteli jade tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́.
4Elijah si wi fun u pe, Eliṣa, emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitori ti Oluwa rán mi si Jeriko. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn de Jeriko.
5Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Jeriko tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si dahùn wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́.
6Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Jordani. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Awọn mejeji si jùmọ nlọ.
7Adọta ọkunrin ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro lati wò lòkere rére: awọn mejeji si duro li ẹba Jordani.
8Elijah si mu agbáda rẹ̀, o si lọ́ ọ lù, o si lù omi na, o si pin wọn ni iyà sihin ati sọhun, bẹ̃ni awọn mejeji si kọja ni ilẹ gbigbẹ.
9O si ṣe, nigbati nwọn kọja tan, ni Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ìlọ́po meji ẹmi rẹ ki o bà le mi.
10On si wipe, Iwọ bère ohun ti o ṣoro: ṣugbọn, bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃ kọ, kì yio ri bẹ̃.
11O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, ti nwọn nsọ̀rọ, si kiyesi i, kẹkẹ́ iná ati ẹṣin iná si là ãrin awọn mejeji; Elijah si ba ãjà gòke re ọrun.
12Eliṣa si ri i, o si kigbe pe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. On kò si ri i mọ: o si di aṣọ ara rẹ̀ mu, o si fà wọn ya si meji.
13On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si pada sẹhin, o si duro ni bèbe Jordani.
14On si mu agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si lù omi na, o si wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun Elijah wà? Nigbati on pẹlu si lù omi na, nwọn si pinyà sihin ati sọhun: Eliṣa si rekọja.
15Awọn ọmọ awọn woli ti o wà ni Jeriko nihà keji si ri i, nwọn si wipe, Ẹmi Elijah bà le Eliṣa. Nwọn si wá ipade rẹ̀; nwọn si tẹ̀ ara wọn ba silẹ niwaju rẹ̀.
16Nwọn si wi fun u pe, Wò o na, ãdọta ọkunrin alagbara mbẹ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ; awa bẹ̀ ọ, jẹ ki nwọn ki o lọ, ki nwọn ki o si wá oluwa rẹ lọ: bọya Ẹmi Oluwa ti gbé e sokè, o si ti sọ ọ sori ọkan ninu òke nla wọnni, tabi sinu afonifojì kan. On si wipe, Ẹ máṣe ranṣẹ.
17Nigbati nwọn si rọ̀ ọ titi oju fi tì i, o wi fun wọn pe, Ranṣẹ. Nitorina nwọn rán ãdọta ọkunrin, nwọn si wá a ni ijọ mẹta, ṣugbọn nwọn kò ri i.
18Nwọn si tun pada tọ̀ ọ wá, (nitori ni Jeriko li o joko,) o wi fun wọn pe, Emi kò ti wi fun nyin pe, Ẹ máṣe lọ?
Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Eliṣa
19Awọn ọkunrin ilu na si wi fun Eliṣa pe, Kiyesi i, itẹ̀do ilu yi dara, bi oluwa mi ti ri i: ṣugbọn omi buru, ilẹ si ṣá.
20On si wipe, Mu àwokóto titun kan fun mi wá, si fi iyọ̀ sinu rẹ̀; nwọn si mu u tọ̀ ọ wá.
21On si jade lọ si ibi orisun omi na, o si dà iyọ na sibẹ, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ṣe àwotan omi wọnyi; lati ihin lọ, kì yio si ikú mọ, tabi aṣálẹ.
22Bẹ̃ni a ṣe àwotan omi na titi di oni oloni, gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa ti o sọ.
23O si gòke lati ibẹ lọ si Beteli: bi o si ti ngòke lọ li ọ̀na, awọn ọmọ kekeke jade lati ilu wá, nwọn si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si wi fun u pe, Gòke lọ, apari! gòke lọ, apari!
24O si yipada, o si wò wọn, o si fi wọn bú li orukọ Oluwa. Abo-beari meji si jade lati inu igbó wá, nwọn si fà mejilelogoji ya ninu wọn.
25O si ti ibẹ lọ si òke Karmeli; ati lati ibẹ o pada si Samaria.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.