Eliṣa si tun pada wá si Gilgali, iyàn si mu ni ilẹ na; awọn ọmọ awọn woli joko niwaju rẹ̀: on si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Gbe ìkoko nla ka iná, ki ẹ si pa ipẹ̀tẹ fun awọn ọmọ awọn woli.
Ẹnikan si jade lọ si igbẹ lati fẹ́ ewebẹ̀, o si ri ajara-igbẹ kan, o si ka eso rẹ̀ kún aṣọ rẹ̀, o si rẹ́ ẹ wẹwẹ, o dà wọn sinu ikoko ipẹ̀tẹ na: nitoripe nwọn kò mọ̀ wọn.
Bẹ̃ni nwọn si dà a fun awọn ọkunrin na lati jẹ. O si ṣe bi nwọn ti njẹ ipẹ̀tẹ na, nwọn si kigbe, nwọn si wipe, Iwọ enia Ọlọrun, ikú mbẹ ninu ikoko na! Nwọn kò si le jẹ ẹ.
Ṣugbọn on wipe, Njẹ, ẹ mu iyẹ̀fun wá. O si dà a sinu ikoko na, o si wipe, Dà a fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ. Kò si si jamba ninu ikoko mọ.
Ọkunrin kan si ti Baali-Ṣaliṣa wá, o si mu àkara akọso-eso, ogun iṣu àkara barle, ati ṣiri ọkà titun ninu àpo rẹ̀ wá fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ.
Iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kinla, ki emi ki o gbé eyi kà iwaju ọgọrun enia? On si tun wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ: nitori bayi li Oluwa wi pe, Nwọn o jẹ, nwọn o si kù silẹ.
Bẹ̃li o gbe e kà iwaju wọn, nwọn si jẹ, nwọn si kù silẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.