Li ọdun kẹtadilogoji Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ọdun mẹrindilogun.
On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa; on kò lọ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: ṣugbọn o rìn ninu wọn.
Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi ba Amasiah ọba Juda jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
Joaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Jeroboamu si joko lori itẹ́ rẹ̀: a si sìn Joaṣi ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli.
Eliṣa si ṣe aisàn ninu eyi ti kò ni yè, Joaṣi ọba Israeli si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, o si sọkun si i li oju, o si wipe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀!
Eliṣa si wi fun u pe, Mu ọrun pẹlu ọfà: on si mu ọrun ati ọfà.
O si wi fun ọba Israeli pe, Fi ọwọ rẹ le ọrun na: on si fi ọwọ rẹ̀ le e: Eliṣa si fi ọwọ tirẹ̀ le ọwọ ọba.
O si wipe, Ṣi fèrese ilà õrùn. On si ṣi i. Nigbana ni Eliṣa wipe, Ta. On si ta. O si wipe, Ọfà igbala Oluwa, ati ọfà igbala lọwọ Siria: nitori iwọ o kọlù awọn ara Siria ni Afeki, titi iwọ o fi run wọn.
O si wipe, Kó awọn ọfà na. O si kó wọn. O si wi fun ọba Israeli pe, Ta si ilẹ. On si ta lẹrinmẹta, o si mu ọwọ duro.
Enia Ọlọrun na si binu si i, o si wipe, Iwọ iba ta lẹrinmarun tabi mẹfa; nigbana ni iwọ iba kọlù Siria titi iwọ iba fi run u: ṣugbọn nisisiyi iwọ o kọlù Siria nigbà mẹta.
Eliṣa si kú, nwọn si sìn i. Ẹgbẹ́ awọn ara Moabu si gbé ogun wá ilẹ na li amọdun.
O si ṣe, bi nwọn ti nsinkú ọkunrin kan, si kiye si i, nwọn ri ẹgbẹ́ kan; nwọn si jù ọkunrin na sinu isà-okú Eliṣa; nigbati a si sọ ọ silẹ, ti ọkunrin na fi ara kàn egungun Eliṣa, o si sọji, o si dide duro li ẹsẹ̀ rẹ̀.