Ní ọdún kẹtadinlogoji tí Joaṣi jọba ní Juda ni Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. Òun náà ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya, ọba Juda, jà ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jehoaṣi kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba Israẹli ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Nígbà tí wolii Eliṣa wà ninu àìsàn tí ó le, tí ó sì ń kú lọ, Jehoaṣi, ọba Israẹli lọ bẹ̀ ẹ́ wò, nígbà tí ó rí Eliṣa, ó sọkún, ó sì ń kígbe pé, “Baba mi, baba mi! Ìwọ tí o jẹ́ alátìlẹyìn pataki fún Israẹli!”
Eliṣa bá sọ fún un pé kí ó mú ọrun ati ọfà, ó sì mú wọn. Eliṣa sọ fún un pé kí ó múra láti ta ọfà náà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Eliṣa gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba, ó ní kí ọba ṣí fèrèsé, kí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ọba sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Eliṣa pàṣẹ fún un pé kí ó ta ọfà náà. Bí ọba ti ta ọfà ni Eliṣa ń wí pé, “Ọfà ìṣẹ́gun OLUWA, ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria! Nítorí pé o óo bá àwọn Siria jagun ní Afeki títí tí o óo fi ṣẹgun wọn.”
Eliṣa tún ní kí ọba máa ta àwọn ọfà yòókù sílẹ̀. Nígbà tí ó ta á lẹẹmẹta, ó dáwọ́ dúró. Èyí bí Eliṣa ninu, ó sì sọ fún ọba pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o ta ọfà náà nígbà marun-un tabi mẹfa ni, ò bá ṣẹgun Siria patapata, ṣugbọn báyìí, ìgbà mẹta ni o óo ṣẹgun wọn.”
Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀.
Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.