II. A. Ọba 13:10-21

II. A. Ọba 13:10-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

Li ọdun kẹtadilogoji Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ọdun mẹrindilogun. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa; on kò lọ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: ṣugbọn o rìn ninu wọn. Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi ba Amasiah ọba Juda jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Joaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Jeroboamu si joko lori itẹ́ rẹ̀: a si sìn Joaṣi ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli. Eliṣa si ṣe aisàn ninu eyi ti kò ni yè, Joaṣi ọba Israeli si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, o si sọkun si i li oju, o si wipe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀! Eliṣa si wi fun u pe, Mu ọrun pẹlu ọfà: on si mu ọrun ati ọfà. O si wi fun ọba Israeli pe, Fi ọwọ rẹ le ọrun na: on si fi ọwọ rẹ̀ le e: Eliṣa si fi ọwọ tirẹ̀ le ọwọ ọba. O si wipe, Ṣi fèrese ilà õrùn. On si ṣi i. Nigbana ni Eliṣa wipe, Ta. On si ta. O si wipe, Ọfà igbala Oluwa, ati ọfà igbala lọwọ Siria: nitori iwọ o kọlù awọn ara Siria ni Afeki, titi iwọ o fi run wọn. O si wipe, Kó awọn ọfà na. O si kó wọn. O si wi fun ọba Israeli pe, Ta si ilẹ. On si ta lẹrinmẹta, o si mu ọwọ duro. Enia Ọlọrun na si binu si i, o si wipe, Iwọ iba ta lẹrinmarun tabi mẹfa; nigbana ni iwọ iba kọlù Siria titi iwọ iba fi run u: ṣugbọn nisisiyi iwọ o kọlù Siria nigbà mẹta. Eliṣa si kú, nwọn si sìn i. Ẹgbẹ́ awọn ara Moabu si gbé ogun wá ilẹ na li amọdun. O si ṣe, bi nwọn ti nsinkú ọkunrin kan, si kiye si i, nwọn ri ẹgbẹ́ kan; nwọn si jù ọkunrin na sinu isà-okú Eliṣa; nigbati a si sọ ọ silẹ, ti ọkunrin na fi ara kàn egungun Eliṣa, o si sọji, o si dide duro li ẹsẹ̀ rẹ̀.

II. A. Ọba 13:10-21 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún kẹtadinlogoji tí Joaṣi jọba ní Juda ni Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun. Òun náà ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya, ọba Juda, jà ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jehoaṣi kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba Israẹli ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí wolii Eliṣa wà ninu àìsàn tí ó le, tí ó sì ń kú lọ, Jehoaṣi, ọba Israẹli lọ bẹ̀ ẹ́ wò, nígbà tí ó rí Eliṣa, ó sọkún, ó sì ń kígbe pé, “Baba mi, baba mi! Ìwọ tí o jẹ́ alátìlẹyìn pataki fún Israẹli!” Eliṣa bá sọ fún un pé kí ó mú ọrun ati ọfà, ó sì mú wọn. Eliṣa sọ fún un pé kí ó múra láti ta ọfà náà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Eliṣa gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba, ó ní kí ọba ṣí fèrèsé, kí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ọba sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Eliṣa pàṣẹ fún un pé kí ó ta ọfà náà. Bí ọba ti ta ọfà ni Eliṣa ń wí pé, “Ọfà ìṣẹ́gun OLUWA, ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria! Nítorí pé o óo bá àwọn Siria jagun ní Afeki títí tí o óo fi ṣẹgun wọn.” Eliṣa tún ní kí ọba máa ta àwọn ọfà yòókù sílẹ̀. Nígbà tí ó ta á lẹẹmẹta, ó dáwọ́ dúró. Èyí bí Eliṣa ninu, ó sì sọ fún ọba pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o ta ọfà náà nígbà marun-un tabi mẹfa ni, ò bá ṣẹgun Siria patapata, ṣugbọn báyìí, ìgbà mẹta ni o óo ṣẹgun wọn.” Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀. Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.

II. A. Ọba 13:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọdún kẹtà-dínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Ó ṣe búburú ní ojú OLúWA, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn. Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jehoaṣi fún ìgbà tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? Jehoaṣi sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. Jeroboamu sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́. A sin Jehoaṣi sí Samaria pẹ̀lú àwọn ọba Israẹli. Nísinsin yìí, Eliṣa ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jehoaṣi ọba Israẹli lọ láti lọ wò ó, ó sì sọkún lórí rẹ̀. “Baba mi! Baba mi!” Ó sọkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Israẹli!” Eliṣa wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. “Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Israẹli. Nígbà tí ó ti mú u, Eliṣa mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba. “Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun OLúWA; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.” Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Eliṣa wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró. Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùnún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà; Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n Nísinsin yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré.” Eliṣa kú a sì sin ín. Ẹgbẹ́ Àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún. Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì: Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀.