II. A. Ọba 13
13
Jehoahasi Ọba Israẹli
1LI ọdun kẹtalelogun Joaṣi ọmọ Ahasiah ọba Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria.
2On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, o si tẹ̀le ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: on kò si lọ kuro ninu rẹ̀.
3Ibinu Oluwa si rú si Israeli, o si fi wọn le ọwọ Hasaeli ọba Siria, ati le ọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, li ọjọ wọn gbogbo.
4Jehoahasi si bẹ̀ Oluwa, Oluwa si gbọ́ tirẹ̀; nitoriti o ri inira Israeli, nitoriti ọba Siria ni wọn lara.
5Oluwa si fun Israeli ni olugbala kan, bẹ̃ni nwọn si bọ́ lọwọ awọn ara Siria: awọn ọmọ Israeli si joko ninu agọ wọn bi ìgba atijọ.
6Ṣugbọn nwọn kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ṣugbọn nwọn rìn ninu rẹ̀: ere-oriṣa si wà ni Samaria pẹlu.
7Bẹ̃ni kò kù ninu awọn enia fun Jehoahasi, bikòṣe ãdọta ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́ mẹwa, ati ẹgbãrin ẹlẹsẹ̀; nitoriti ọba Siria ti pa wọn run, o si ti lọ̀ wọn mọlẹ bi ẽkuru.
8Ati iyokù iṣe Jehoahasi, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
9Jehoahasi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i ni Samaria: Joaṣi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Jehoaṣi Ọba Israẹli
10Li ọdun kẹtadilogoji Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ọdun mẹrindilogun.
11On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa; on kò lọ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀: ṣugbọn o rìn ninu wọn.
12Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi ba Amasiah ọba Juda jà, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
13Joaṣi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Jeroboamu si joko lori itẹ́ rẹ̀: a si sìn Joaṣi ni Samaria pẹlu awọn ọba Israeli.
Ikú Eliṣa
14Eliṣa si ṣe aisàn ninu eyi ti kò ni yè, Joaṣi ọba Israeli si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, o si sọkun si i li oju, o si wipe, Baba mi, baba mi! kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀!
15Eliṣa si wi fun u pe, Mu ọrun pẹlu ọfà: on si mu ọrun ati ọfà.
16O si wi fun ọba Israeli pe, Fi ọwọ rẹ le ọrun na: on si fi ọwọ rẹ̀ le e: Eliṣa si fi ọwọ tirẹ̀ le ọwọ ọba.
17O si wipe, Ṣi fèrese ilà õrùn. On si ṣi i. Nigbana ni Eliṣa wipe, Ta. On si ta. O si wipe, Ọfà igbala Oluwa, ati ọfà igbala lọwọ Siria: nitori iwọ o kọlù awọn ara Siria ni Afeki, titi iwọ o fi run wọn.
18O si wipe, Kó awọn ọfà na. O si kó wọn. O si wi fun ọba Israeli pe, Ta si ilẹ. On si ta lẹrinmẹta, o si mu ọwọ duro.
19Enia Ọlọrun na si binu si i, o si wipe, Iwọ iba ta lẹrinmarun tabi mẹfa; nigbana ni iwọ iba kọlù Siria titi iwọ iba fi run u: ṣugbọn nisisiyi iwọ o kọlù Siria nigbà mẹta.
20Eliṣa si kú, nwọn si sìn i. Ẹgbẹ́ awọn ara Moabu si gbé ogun wá ilẹ na li amọdun.
21O si ṣe, bi nwọn ti nsinkú ọkunrin kan, si kiye si i, nwọn ri ẹgbẹ́ kan; nwọn si jù ọkunrin na sinu isà-okú Eliṣa; nigbati a si sọ ọ silẹ, ti ọkunrin na fi ara kàn egungun Eliṣa, o si sọji, o si dide duro li ẹsẹ̀ rẹ̀.
Ogun Láàrin Israẹli ati Siria
22Ṣugbọn Hasaeli ọba Siria ni Israeli lara ni gbogbo ọjọ Jehoahasi.
23Oluwa si ṣe oju rere si wọn, o si ṣãnu fun wọn, o si ṣe akiyesi wọn, nitoriti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, kò si fẹ run wọn, bẹ̃ni kò si ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀ titi di isisiyi.
24Bẹ̃ni Hasaeli ọba Siria kú; Benhadadi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
25Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi si tun gbà ilu wọnni pada lọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, ti o ti fi ogun gbà lọwọ Jehoahasi baba rẹ̀. Igba mẹta ni Joaṣi ṣẹgun rẹ̀, o si gbà awọn ilu Israeli pada.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 13: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.