JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ

“Ikú ti Ikú”
Jésù ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ pé, “Màá jíǹde ní ọjọ́ kẹta.” Ó sọọ́ nínú Máàkù 8, àti ní Máàkù 9, Ó tún tún un sọ ní Máàkù 10.
Látàrí àtúnwí yìí, ohun kàyéèfì kan ń lọ lọ́wọ́. Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ikú Jésù, kò sí ọmọ ẹ̀hìn l'ọ́kùnrin kankan nítòsíí; àwọn ọmọ ẹ̀hìn l'óbìnrin yìí y'ọjú, ṣùgbọ́n wọ́n kó gbogbo ìkunra olóòrùn dídùn olówó iyebíye dání irú èyí tí a fi màá ń kun òkú lára. Kò sí ẹni tí ó ńretí àjíǹde. Bí o bá jẹ́ òǹkọ̀wé Ìhìnrere Máàkù, tí ò ń tiraka láti kọ ìtàn àpilẹ̀kọ, tí o sì ti gbọ́ tí Jésù sọ ní àìmọye ìgbà fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ pé Òun yíó jíǹde ní ọjọ́ kẹta, ṣe o kò níí ni ó kéré jù ọmọ ẹ̀hìn kan tí yíó ronú nípa èyí lẹ́yìn ikú Jésù tí yíò sì sọ fún àwọn yòókù pé, “Ẹ wo 'bí, òní l'ọjọ́ kẹta. Bóyá ká lọ wo ibojì Jésù. Kíní fi ń ṣ'ènìyàn?” Èyí mú ọgbọ́n wá àbí? Ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí ó sọ bẹ́ẹ̀. Kódà, wọn kò retí àjíǹde rárá. Kò kọ sí wọn lọ́kàn. Ańgẹ́lì tó wà níwájú ibojì ní láti ràn àwọn obìnrin náà létí pé: “Ẹ ó rí I, gẹ́gẹ́ bí Ó ti sọ fún yín.” Bí ó bá jẹ́ pé Máàkù kàn ro ìtàn yí sọ ni, kò níí kọọ́ báyìí.
Kókó ibẹ̀ nìyìí: Àjíǹde kò ṣeé f'òye gbé fún àwọn ọmọ èhìn àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣòro láti gbàgbọ́ fún wọn bíi ti t'ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa náà lónìí. Lóòtọ́, èrèdí àìgbàgbọ́ wọn lè yàtọ̀ sí tiwa. Àwọn Gíríkì kò gbàgbọ́ nínú àjíǹde; ní ìwòye àwọn Gíríkì, ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú ni ìdáǹdè ẹ̀mí kúrò nínú ara. Fún wọn àjíǹde kò lè jẹ́ ara ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú láí. Fún àwọn Júù ní tiwọn, àwọn kan gbàgbọ́ nínú àjíǹdé gbogboogbò níbití gbogbo àgbáyé yíó ti di ọ̀tun, ṣùgbọ́n wọn kò ní òye kí ẹnikọ̀ọ̀kan jíǹde nínú òkú. Àwọn ènìyàn ìgbà ayé Jésù kò gbàgbọ́ nínú àjíǹde ju ti tàwa náà lọ lónìí.
Ǹjẹ́ ó ṣòro fún ọ láti gbàgbọ́ pé Jésù jíǹde kúrò nínú òkú? Báwo ni àjíǹde Jésù ṣe fún ọ ní ìrètí?
Àyọkà láti inú JÉSÙ ỌBA NÁÀ l'átọwọ́ Timothy Keller
Àtúntẹ̀ pẹ̀lù àsọyé pẹ̀lú Riverhead Books, ọ̀kan lára Penguin Group (USA) LLC, ti Ilé-iṣẹ́ Penguin Random House. Copyright © 2011 l'átọwọ́ Timothy Keller
Àti láti inú ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ JÉSÙ ỌBA NÁÀ l'átọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Copyright (c) 2015 l'átọwọ Zondervan, ẹ̀ka Ilé-iṣẹ́ Ìwé Krìstíẹ́nì ti HarperCollins.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.
More
Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide