JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ

JESUS THE KING: An Easter Devotional By Timothy Keller

Ọjọ́ 7 nínú 9

“Ìdàpọ̀-Mímọ́ àti Àwùjọ”

Rántí ohun tí Jésù sọ nígbàtí Ó gbé ago:

Ó sì gbé ago, nígbàtí Ó sì súré tán, Ó fi fún wọn, gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, "Èyí ni ẹ̀jẹ̀ Mi ti májẹ̀mú titun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Lóòtọ́ ni Mo wí fún yín, Èmi kì yíó mu nínú èso àjàrà mọ́, títí yíó fi di ọjọ́ náà, nígbàtí Èmí ó mu ú ní titun ní ìjọba Ọlọ́run."
(Máàkù 14:23–25)

Ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí pé látàrí ìfararúbọ onípàṣípààrọ̀ Rẹ̀, májẹ̀mú titun ti wà báyìí láàrin Ọlọ́run àti àwa. Ìpìlẹ̀ ìbáṣepọ̀ yìí sì ni ẹ̀jẹ̀ Jésù fúnrarẹ̀: “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi.” Nígbàtí Ó kéde rẹ̀ pé Òun kò níí mu tàbí jẹ nínú rẹ̀ mọ́ títí Òun yíó fi pàdé wà ní ìjọba Ọlọ́run, Jésù ń ṣèlérí fún wa pé Òun fi ara jì fún wa láìní kọ́núukọ̀ọ kankan nínú: “Èmi yíó mú yín padà wá sí apá Bàbá. Èmi yíó mú yín wá sí bi àsè Ọba náà.” L'ọ́pọ̀ ìgbà ni Jésù màá ń fi ìjọba Ọlọ́run ṣ'àkàwé jíjókòó sí ibi àsè ńlá. Ní Mátíù 8, Jésù wípé, “Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yíó ti ìhà ìlà-õrùn àti ìhà ìwọ̀-õrùn wá, wọn á sì jókòó ní ibi àsè . . . ní ìjọba ọ̀run.” Jésù ṣ'èlérí pé a ó wà ní ibi àsè ìjọba yìí pẹ̀lú Òun.

Pẹ̀lú àwọn ìṣe pẹ̀lẹ́ bíi gbígbé àkàrà àti wáìnì sókè, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ bíi “Èyí ni ẹran-ara mi . . . Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi,” Jèsù ǹ sọ fún wa pé àwọn ìtúsílẹ̀ ìṣáájú, ẹbọ ìṣáájú, ọ̀dọ́-àgùntàn ní Ìrékọjá ń toka sí Òun. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣe Ìrékọjá àkọ́kọ́ ní òru ṣáájú ọjọ́ tí Ọlọ́run yíó ra Ísráèlì padà l'óko ẹrú nípa ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn, a jẹ àsè Ìrékọjá yìí ní òru ṣáájú kí Ọlọ́run tó rà aráyé padà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nípa ẹ̀jẹ̀ Jésù.

Kíni àwọn ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ nínú ọkàn àti ẹ̀mí rẹ kí o baá lè fi tọkàntọkàn gba ohun tí Jésù ń fi lọ̀ ọ́?

Àyọkà kan láti inú ìwé JESUS THE KING, látọwọ́ Timothy Keller
A tẹ̀ ẹ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn pẹ̀lú Riverhead Books, ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Group (USA) LLC, A Penguin Random House Company. Àṣẹ ìtẹ̀jáde © 2011 látọwọ́ Timothy Keller

Àti láti inú ìwé JESUS THE KING STUDY GUIDE látọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Àṣẹ ìtẹ̀jáde (c) 2015 látọ̀dọ̀ Zondervan, ẹ̀ka kan ti HarperCollins Christian Publishers.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6Ọjọ́ 8

Nípa Ìpèsè yìí

JESUS THE KING: An Easter Devotional By Timothy Keller

Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.

More

Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide