JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ

JESUS THE KING: An Easter Devotional By Timothy Keller

Ọjọ́ 5 nínú 9

"Jésù ní láti Kú”

Nípa lílo ọ̀rọ̀ gbọ́dọ̀, Jésù ń tọ́ka pé òun ń gbèrò láti kú—pé ó jẹ́ ohun tí ó ti inú rẹ̀ wá. Kìí ṣe pé ó kàn sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé yíò ṣẹlẹ̀ lásán. Eyi ni ohun ti ó dàbí ohun tí ó ṣe okùnfà ìbínú Pétérù jùlọ. Oun kan ni kí Jésù sọ wípé, “Èmi yíò jà a ó sí ṣẹ́gun mi," ọ̀tọ̀ sì ni kí Ó tún sọ pé, “Èyí ni ìdí tí mo fi wá; mo pinnu lati ku!” Èyí jẹ́ ohun tó rúnilójú paraku sí Pétérù.

Ìdí nìyí ti ó fí jẹ́ pé ní kété tí Jésù sọ èyí, Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí “bàa wí.” Èyí ni ọ̀rọ̀-ìṣe tí a lò ní ibòmíràn fún ohun tí Jésù ṣe sí àwọn ẹ̀mí èṣù. Èyí túmọ̀ sí pé Pétérù ń dá Jésù lẹ́bi pẹ̀lú èdè tí ó lágbára jùlọ. Kíni ìdí tí Pétérù fi f'araya, tó fi lè kojú sí Jésù báyìí lẹ́hìn tí ó ti ṣe ìdánimọ̀ rẹ̀ bi Olùgbàlà? Láti kékeré ní ìyá Pétérù ti kọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé nígbàtí Olùgbàlà bá dé, Òun yíò ṣẹ́gun ibi àti àìṣòdodo nípa gígun orí ìtẹ́. Ṣùgbọ́n Jésù ń sọ níbí pé, “Bẹ́ẹ̀ni, Èmi ni Olùgbàlà náà, Ọba náà, ṣùgbọ́n èmi kò wá láti wà láàyè ṣùgbọ́n láti kú. Èmi kò wá láti gba agbára ṣùgbọ́n láti pàdánù rẹ̀; Èmi kò wá níbí láti ṣe àkóso ṣùgbọ́n láti sìn. Báyìí ní Un ó ṣe ṣẹ́gun ibi tí Un ó sì ṣé àtúnṣe ohun gbogbo.

”Jésù kò kàn sọpé Ọmọ Ènìyàn yíò jìyà; Ó sọpé Ọmọ Ènìyàn gbọ́dọ̀ jìyà. Ọ̀rọ̀ yí ṣe pàtàkì débi pé a ṣe àmúlò rẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì: “Ọmọ Ènìyàn gbọdọ jiya ohun púpọ̀ . . . a sì gbọ́dọ̀ paá. "Ọ̀rọ̀ náà, gbọ́dọ̀ ṣe ìyípadà ati ìṣàkóso gbogbo gbólóhùn yẹn, ó sì túmọ̀ sí pé ohun gbogbo nínú àtòjọ yí ni ó pàtàkì. Jésù gbọ́dọ̀ jìyà, ó gbọ́dọ̀ di ìkọ̀sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ paá, ó sì gbọ́dọ̀ jíǹde . Èyí jẹ́ ọkan nínú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì jùlọ nínú ìtàn àgbáyé, ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó dẹ́rùbani. Ohun ti Jesu sọ kìí ṣe “Mo wá lati kú ” ṣugbọn “Mo ni láti kú. Ó jẹ́ dandan pé kí n kú. Ayé kò lè ṣée tún ṣe, bákannáà ìgbésí ayé rẹ pẹ̀lú, àyàfi tí mo bá kú.” Kíni ìdí tí ó fí jẹ́ dandan àìmáṣe fún Jésù láti kú?

Ó nira fún Pétérù láti rí ìwúlò ikú Jésù. Kíni ìdí tí èyí fi nira fún u—àti fún àwa náà—láti tẹ́wọ́ gbáà?

Àyọkà kan láti inú ìwé JESUS THE KING, látọwọ́ Timothy Keller
A tẹ̀ ẹ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn pẹ̀lú Riverhead Books, ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Group (USA) LLC, A Penguin Random House Company. Àṣẹ ìtẹ̀jáde © 2011 látọwọ́ Timothy Keller

Àti láti inú ìwé JESUS THE KING STUDY GUIDE látọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Àṣẹ ìtẹ̀jáde (c) 2015 látọ̀dọ̀ Zondervan, ẹ̀ka kan ti HarperCollins Christian Publishers.


IDAGBASOKE

 
Bọtini: ọjọ_5

ọjọ_5.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

JESUS THE KING: An Easter Devotional By Timothy Keller

Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.

More

Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide