JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ
"Ìpè láti ọ̀dọ̀ Ọba"
Ìhìnrere kì í ṣe ìmọ̀ràn: irohìn rere ni pé o kò nílò láti ṣe iṣẹ́ rere láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; Jésù ti ṣe é fún ọ. Ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan tí o kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ni-tí o sì rí gbà láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Tí o bá gba ẹ̀bùn yẹn, tí o sì ń ṣiṣẹ́ síwájú àti síwájú, ìpè Jésù kò ní sọ ọ di alákatakítí tàbí òní jẹ̀lẹ́nkẹ́. Ìwọ yóò ní ìtara láti fi Jésù ṣe àfojúsùn rẹ àti ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, láti máa rìn yí i ká; síbẹ̀ nígbà tí o bá pàdé ẹnì tó ní àwọn irúfẹ́ àfojúsùn tó yàtọ̀, tó ní ìgbàgbọ́ tó yàtọ̀ sí tìẹ, o kò ní fi ojú pa wọ́n rẹ́. Ìwọ náà á máa sìn wọ́n dípò tí wàá fi máa ni wọ́n lára.
Kí nìdí? Nítorí pé ìhìnrere kì í ṣe nípa yíyan láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn, ó já sí ìpè láti tẹ̀lé Ọba kan. Kì í ṣe ẹnìkan tó ní agbára àti àṣẹ láti sọ ohun tó yẹ kó o ṣe fún ọ nìkan— bí kò ṣe ẹni tó ní agbára àti àṣẹ láti ṣe ohun tó yẹ kí ó ṣe, kó sì wá fi fún ọ gẹ́gẹ́bí ìhìnrere.
Ibo la ti lè rí irú àṣẹ bẹ́ẹ̀? Àwọn àmì àràmàǹdà tó fi hàn pé Jésù ní àṣẹ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ti wáyé ṣáájú ìrìbọmi rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a rí Símónì, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù tí wọ́n tẹ̀lé Jésù láìjáfara—èyí fi hàn pé ìpè rẹ̀ ní àṣẹ. Máàkù ń tẹ̀síwájú láti mọ lé kókó yìí:
"Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ìlú Kapernaumu, nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi, ó lọ sínú Sinagọgu, ó sì ń kọ́ni. Ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn nítorí ìkọ́ni rẹ̀, nítorí pé ó ń kọ́ni bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn olùkọ́ òfin ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn."
(Máàkù 1:21)
Máàkù lo ọ̀rọ̀ yìí "àṣẹ" fún ìgbà àkọ́kọ́; ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ní pàtó ni, "láti inú ojúlówó èròjà.” Ọ̀rọ̀ náà wá látinú ọ̀rọ̀ kan náà tí wọ́n fi ń pe òǹkọ̀wé. Ohun tí Máàkù ń sọ ni pé Jésù ń kọ́ni nípa ìgbésí ayé, pẹ̀lú ojúlówó àṣẹ dípò èyí tí a rí e.
Báwo ni ìgbésí ayé rẹ ṣe máa rí tó o bá fi ara rẹ sábẹ́ Ọba pípé yìí? Bí o ṣe ń ṣiṣẹ́? Bí o ṣe ńlo ìfẹ́? Ètò ìdílé? Ètò ìṣúnná owó? Ìgbé ayé láwùjọ?
Àyọkà kan láti inú ìwé JESUS THE KING, látọwọ́ Timothy Keller
A tẹ̀ ẹ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn pẹ̀lú Riverhead Books, ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Group (USA) LLC, A Penguin Random House Company. Àṣẹ ìkọ̀wé © 2011 látọwọ́ Timothy Keller
Àti láti inú ìwé JESUS THE KING STUDY GUIDE látọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Àdàkọ: Copyright (c) 2015 látọ̀dọ̀ Zondervan, ẹ̀ka kan ti HarperCollins Christian Publishers.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.
More
Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide