JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ

JESUS THE KING: An Easter Devotional By Timothy Keller

Ọjọ́ 2 nínú 9

Ìwòsàn tó Jinlẹ̀”

Jésù mọ ohun tí arákùnrin yìí kò mọ — pé ó ní ìṣòro tí ó tóbi púpọ̀ ju ipò tí àgó ara rẹ̀ wà lọ. Jésù n sọ fún un pé, “Mo lóye àwọn ìṣòro rẹ. Mo ti rí ìyà rẹ. Èmi yóò wá fi àbọ̀ bá iyẹn. Ṣùgbọ́n jọ̀wọ́ mọ̀ dájú pé kókó ìṣòro nínú ìgbésí ayé ènìyàn kìí ṣe ìyà tó ńjẹ ẹ́; ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni."

Tí ìdáhùn Jésù bá fà ìbínú, jọ̀wọ́ tí lẹ̀ fi èrò sí èyí: Tí ẹnìkan bá sọ fún ọ, “Kókó ìṣòro ìgbésí ayé rẹ kìí ṣe ohun ti o ṣẹ lẹ̀ sí ọ, bẹ̀ẹ́ ní kìí ṣe ohun ti ènìyàn ti ṣe sí ọ; kókó ìṣòro rẹ ni ìhùwàsí rẹ̀ sí ohun tí a ṣe sí ọ” — ọ̀rọ̀ yí nídàkéjì, ó ń fi àgbàrá fúnọ. Báwo? Nítorí kò sí ohun tí o lè ṣe nípa ohun tí tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ tàbí nípa ohun tí àwọn ènìyàn míràn ńṣe — ṣùgbọ́n o lè ṣe ǹkankan nípa ara rẹ. Nígbàtí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ kìí ṣé pé ó tọ́ka sí àwọn ohun búburú tí a ṣe. Bẹ̀ẹ́ni kìí ṣe irọ́ tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ ara tàbí ohunkóhun ti ọ̀ràn náà lé jẹ́ — ó jẹ́ fí fi ojú di Ọlọ́run nínú ayé tí ó dá; ó sì jẹ́ ìṣọ̀tẹ̀ sí i nípa gbígbé láìsí ìtọ́ka sí ẹnití ó dá wa. Bíi ká ma sọ pé, “Màá dá gbèrò fún rárá mi bí mo ṣe fẹ́ gbé ìgbésí aye mi.” Jésù sọ pé kókó ìṣòro wa nìyí.

Jésù ń dojúkọ alárùn ẹ̀gbà náà pẹ̀lú kókó ìṣòro rẹ̀ nípa mímú ún jinlẹ̀ sí. Jésù ń sọ wípé, “Bí ó ṣe wá sí ọ̀dọ̀ mí tí ó bèèrè fún ìmúláradá ara rẹ nìkan kò jinlẹ̀ tó. O ti fojú tẹ́mbẹ́lú bí àwọn ìpòngbẹ́ rẹ ṣe jìn tó, àwọn ìpòngbẹ́ ọkàn rẹ̀”. Ẹnikẹ́ni tí ó rọpárọsẹ̀ láti ìgbà ìbí ni yóò fẹ́ ṣe ohunkóhun lati rin. Nítòótọ́ ọkùnrin yìí ti sinmi nínú gbogbo àwọn ìrètí rẹ̀ pé ó ṣeéṣe fún òun láti rìn lẹ́ẹ̀kansi. Nínú ọkàn rẹ̀ o fẹ́rẹ̀ sọ pé, “Tí mo bá lè rìn lẹ́ẹ̀kan si, gbogbo ǹkan yókù kéré. Kò sí ohun tí yóò bà mí nínú jẹ́ mọ́, bẹ̀ẹ́ ní kò ní sí àròyé mọ́. Tí mo bá bá kàn lè rìn, lẹhin náà ohun gbogbo yíò ṣé dédé.” Jésù ń sọ wípé, “ Ọmọ mi, àṣìṣe ní eléyìí jẹ́.” Ìyẹn lè jẹ́ ohun tí ó nira láti gbọ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ òtítọ́ tí ó jinlẹ̀. Jésù sọ wípé, “Nigbati mo bá mú ọ lára dá, tí ó bá jẹ́kìkì ǹkan tí mo ṣe nìyí, yíò dàbí pe o kò ní banújẹ mọ́. Ṣùgbọ́n dúró oṣù méjì, tàbí oṣù mẹ́rin — ìdùnnú rẹ kò leè lọ títí. Àwọn gbòǹgbò àìnítẹ́lọ̀rùn ọkàn ènìyàn jìn púpọ̀."

”Kíni ìdí tí ìdáríjì fi jẹ́ àìní tí ó jinlẹ̀ jù fún alárùn-ẹ̀gbà yí? Kíni ìdí tí ó fi jẹ́ àìní tí ó jinlẹ̀ jù fúnìwọnáà? Kíni àwọn "àìní" míràn tí a rò pé ó jinlẹ̀ jú ìdáríjì lọ?

Àyọkà kan láti inú ìwé JESUS THE KING, látọwọ́ Timothy Keller
A tẹ̀ ẹ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn pẹ̀lú Riverhead Books, ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Group (USA) LLC, A Penguin Random House Company. Àṣẹ ìtẹ̀jáde © 2011 látọwọ́ Timothy Keller

Àti láti inú ìwé JESUS THE KING STUDY GUIDE látọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Àṣẹ ìtẹ̀jáde (c) 2015 látọ̀dọ̀ Zondervan, ẹ̀ka kan ti HarperCollins Christian Publishers.

IDAGBASOKE

 

Bọtini: ọjọ_2.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

JESUS THE KING: An Easter Devotional By Timothy Keller

Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.

More

Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide