JÉSÙ ỌBA NÁÀ: Ètò Ìfọkànsìn fún Àjíǹde láti ọwọ́ Timothy KellerÀpẹrẹ

Ó Ju Bí O Ṣe Rò Lọ
Nígbà míràn tí mo bá tọ Jésù lọ, ó máa ń jẹ́ kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ tí mi ò lóye. Kì í ṣe ohun tí mo ní lọ́kàn ni ó máa ń ṣe, tàbí kí ó ṣe é ní ọ̀nà tó ní ìtumọ̀ sí mi. Ṣùgbọ́n bí Jésù bá jẹ́ Ọlọ́run, ó ní láti jẹ́ pé ó tóbi débi pé ó ní àwọn ìdí kan tó fi jẹ́ kí o la àwọn ohun tí kò yé ọ kọjá. Agbára rẹ̀ kò ní ààlà, bákannáà ni ọgbọ́n àti ìfẹ́ rẹ̀. Ọ̀ràn rẹ kò kan àbùdá rárá, àmọ́ Jésù ní ìfẹ́ tí kò ṣe é pa lẹ́nu mọ́ fún ọ. Ká ní àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ lóòótọ́ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ni, ká ní òye yé wọn lóòótọ́ pé Jésù lágbára àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn ni, ì bá máà sí ìbẹ̀rù kankan nínú wọn. Àgbọ́kànlé wọn pé tí Jésù bá nífẹ̀ẹ́ wọn, kò ní jẹ́ kí búburú ṣẹlẹ̀ sí wọn, kùnà. Ó lè nífẹ̀ẹ́ ẹni, kó sì ṣì jẹ́ kí nǹkan búburú ṣẹlẹ̀ sí i, nítorí pé òun ni Ọlọ́run, nítorí pé òun mọ ohun tó sàn ju ẹni náà lọ.
Tí o bá ní Ọlọ́run kan tó tóbi tó o sì lágbára tó láti bínú sí nítorí pé kò dáwọ́ ìyà rẹ dúró, o tún ní Ọlọ́run kan tó tóbi tó o sì lágbára tó láti ní àwọn ìdí tí o kò lè lóye. O kò lè ní ohun méjèèjì. Elisabeth Elliot tó jẹ́ olùkọ́ mi sọ ọ́ ní gbólóhùn méjì tó fani mọ́ra: "Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run, níwọ̀n bó ti jẹ́ Ọlọ́run, ó yẹ kí n máa jọ́sìn rẹ̀, kí n sì máa sìn ín. Mi ò lè rí ìsinmi ní ibòmíràn bí kò ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ yí kò lópin, kò ní òdiwọ̀n, kò ṣe fẹnu sọ tán ju ohun gbogbo tí mo lè rò pé ó ní lọ́kàn láti ṣe." Tí o bá wà ní abé ìjì, agbára rẹ̀ kò ní àkàwé, kò sì ní fi ìfẹ́ hàn sí ọ. Ibi kan ṣoṣo tí o ti lè wà ní àìléwu ni nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nítorí pé òun ni Ọlọ́run, kì í sì í ṣe ìwọ, ìfẹ́ Ọlọ́run dájúdájú, kò ní òdiwọ̀n, kò ṣe fẹnu sọ tán ju ohun gbogbo tí o lè rò pé ó ní lọ́kàn láti ṣe." Ǹjẹ́ ó ní ààbò? Ó hàn kedere pé kò ní ààbò. Ta ló sọ pé kò ní séwu? Ṣùgbọ́n ó dára. Òun ni Ọba.
Báwo la ṣe lè ní àlàáfíà nínú Kristi nígbàtí a bá wà nínú ipò tó lè mú ká ṣàníyàn tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì? Ibo ní o ti ń retí pé kí Jésù ràn ọ́ lọ́wọ́?
Àyọkà kan láti inú ìwé JESUS THE KING, látọwọ́ Timothy Keller
A tẹ̀ ẹ́ padà ní ìbámu pẹ̀lú àdéhùn pẹ̀lú Riverhead Books, ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Group (USA) LLC, A Penguin Random House Company. Àṣẹ ìkọ̀wé © 2011 látọwọ́ Timothy Keller
Àti láti inú ìwé JESUS THE KING STUDY GUIDE látọwọ́ Timothy Keller àti Spence Shelton, Àdàkọ: Copyright (c) 2015 látọ̀dọ̀ Zondervan, ẹ̀ka kan ti HarperCollins Christian Publishers.

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ònkọ̀wé atàwàràwàrà ilé ìtẹ̀wé New York Times tí ó tún jẹ́ oníwàásù Timothy Keller pín àwọn àkàwé àtẹ̀lé ra nípa ayé Jésù bí a ti nínú ìwé Máàkù. Tí a bá wo àwọn ìtàn yí fínnífínní, ó mú ìrína ọ̀tun wá sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ayé wa àti ayé ọmọ Ọlọ́run, títí lọ àkókò àjíǹde. JÉSÙ ỌBA NÁÀ ti di ìwé báyìí àti ìlànà ẹ̀kọ́ fún àwọn agbo kéékèèké, ó ńtà kiri ní gbogbo ilé ìtàwé.
More
Àyọkà láti inú àwọn ìwé Riverhead, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Penguin Random House, Ìlànà ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ HarperCollins Christian Publishers. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọsí: http://www.penguin.com/book/jesus-the-king-by-timothy-keller/9781594486661 or http://www.zondervan.com/jesus-the-king-study-guide